1
KỌRINTI KINNI 11:25-26
Yoruba Bible
Bákan náà ni ó mú ife lẹ́yìn oúnjẹ, ó ní, “Èyí ni ife ti majẹmu titun tí a fi ẹ̀jẹ̀ mi dá. Nígbàkúùgbà tí ẹ bá ń mu ún, ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” Nítorí nígbàkúùgbà tí ẹ bá ń jẹ burẹdi yìí, tí ẹ sì ń mu ninu ife yìí, ẹ̀ ń kéde ikú Oluwa títí yóo fi dé.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí KỌRINTI KINNI 11:25-26
2
KỌRINTI KINNI 11:23-24
Nítorí láti ọ̀dọ̀ Oluwa ni mo ti gba ohun tí mo fi kọ yín, pé ní alẹ́ ọjọ́ tí a fi Jesu Oluwa lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, ó mú burẹdi, lẹ́yìn tí ó ti dúpẹ́ tán, ó bù ú, ó ní, “Èyí ni ara mi tí ó wà fun yín. Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”
Ṣàwárí KỌRINTI KINNI 11:23-24
3
KỌRINTI KINNI 11:28-29
Kí olukuluku yẹ ara rẹ̀ wò kí ó tó jẹ ninu burẹdi, kí ó sì tó mu ninu ife Oluwa. Nítorí ẹni tí ó bá ń jẹ, tí ó ń mu láìmọ ìyàtọ̀ tí ó wà ninu ara Kristi, ìdájọ́ ni ó ń jẹ, tí ó sì ń mu, lórí ara rẹ̀.
Ṣàwárí KỌRINTI KINNI 11:28-29
4
KỌRINTI KINNI 11:27
Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń jẹ burẹdi, tabi tí ó ń mu ninu ife Oluwa láìyẹ jẹ̀bi ìlòkulò ara ati ẹ̀jẹ̀ Oluwa.
Ṣàwárí KỌRINTI KINNI 11:27
5
KỌRINTI KINNI 11:1
Ẹ máa fara wé mi bí èmi náà tí ń fara wé Kristi.
Ṣàwárí KỌRINTI KINNI 11:1
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò