Bí wọ́n ti ń jó, wọ́n ń kọrin báyìí pé,
“Saulu pa ẹgbẹẹgbẹrun tirẹ̀,
ṣugbọn Dafidi pa ẹgbẹẹgbaarun tirẹ̀.”
Inú Saulu kò dùn sí orin tí wọ́n ń kọ, inú sì bí i gidigidi. Ó ní, “Wọ́n fún Dafidi ní ẹgbẹẹgbaarun ṣugbọn wọ́n fún mi ní ẹgbẹẹgbẹrun, kí ló kù tí wọn óo fún un ju ìjọba mi lọ.”