wọ́n wí fún un pé, “Wò ó, àgbà ti dé sí ọ, àwọn ọmọ rẹ kò sì tẹ̀lé àpẹẹrẹ rere rẹ. Yan ẹnìkan, gẹ́gẹ́ bí ọba fún wa, tí yóo máa ṣe alákòóso wa bí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.” Ọ̀rọ̀ náà kò dùn mọ́ Samuẹli ninu, pé àwọn eniyan náà ní kí ó fi ẹnìkan jọba lórí wọn. Samuẹli bá gbadura sí OLUWA.