1
KỌRINTI KEJI 6:14
Yoruba Bible
Ẹ má ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ àwọn alaigbagbọ. Nítorí ìrẹ́pọ̀ wo ni ó wà láàrin ìwà òdodo ati aiṣododo? Tabi, kí ni ó pa ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn pọ̀?
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí KỌRINTI KEJI 6:14
2
KỌRINTI KEJI 6:16
Kí ni oriṣa ń wá ninu ilé Ọlọrun? Nítorí ilé Ọlọrun alààyè ni àwa jẹ́. Gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sọ, pé, “N óo máa gbé ààrin wọn, n óo máa káàkiri ní ààrin wọn. N óo jẹ́ Ọlọrun wọn, wọn yóo sì jẹ́ eniyan mi.
Ṣàwárí KỌRINTI KEJI 6:16
3
KỌRINTI KEJI 6:17-18
Nítorí náà ẹ jáde kúrò láàrin wọn, ẹ ya ara yín sọ́tọ̀, ni Oluwa wí. Ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́, kí n lè gbà yín. N óo jẹ́ baba fun yín, ẹ̀yin náà óo sì jẹ́ ọmọ fún mi, lọkunrin ati lobinrin yín. Èmi Oluwa Olodumare ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Ṣàwárí KỌRINTI KEJI 6:17-18
4
KỌRINTI KEJI 6:15
Báwo ni Kristi ti ṣe lè fi ohùn ṣọ̀kan pẹlu Èṣù? Kí ni ìbá pa onigbagbọ ati alaigbagbọ pọ̀?
Ṣàwárí KỌRINTI KEJI 6:15
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò