1
DIUTARONOMI 28:1
Yoruba Bible
“Bí o bá gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun rẹ, tí o sì farabalẹ̀ pa gbogbo òfin rẹ̀, tí mo ṣe fún ọ lónìí mọ́, OLUWA Ọlọrun rẹ yóo gbé ọ ga ju gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù láyé lọ.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí DIUTARONOMI 28:1
2
DIUTARONOMI 28:2
Gbogbo ibukun wọnyi ni yóo mọ́ ọ lórí, tí yóo sì ṣẹ sí ọ lára, bí o bá gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun rẹ.
Ṣàwárí DIUTARONOMI 28:2
3
DIUTARONOMI 28:13
OLUWA yóo fi ọ́ ṣe orí, o kò ní di ìrù; òkè ni o óo máa lọ, o kò ní di ẹni ilẹ̀; bí o bá pa òfin OLUWA Ọlọrun rẹ, tí mo pa láṣẹ fún ọ lónìí mọ́, tí o mú gbogbo wọn ṣẹ lẹ́sẹẹsẹ
Ṣàwárí DIUTARONOMI 28:13
4
DIUTARONOMI 28:12
OLUWA yóo fún ọ ní ọpọlọpọ òjò ní àkókò rẹ̀ láti inú ilé ìṣúra rẹ̀ lójú ọ̀run, yóo sì bukun iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Ìwọ ni o óo máa yá ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ní nǹkan, o kò sì ní tọrọ lọ́wọ́ wọn.
Ṣàwárí DIUTARONOMI 28:12
5
DIUTARONOMI 28:7
“Yóo bá ọ ṣẹgun àwọn ọ̀tá tí ó bá dìde sí ọ. Bí wọ́n bá gba ọ̀nà kan dìde sí ọ, yẹ́lẹyẹ̀lẹ ni wọn óo fọ́nká nígbà tí wọn bá ń sálọ fún ọ.
Ṣàwárí DIUTARONOMI 28:7
6
DIUTARONOMI 28:8
“OLUWA yóo bukun ìkórè inú àká rẹ, ati gbogbo nǹkan tí o bá dáwọ́ lé. OLUWA Ọlọrun rẹ yóo bukun ọ ní ilẹ̀ tí ó fún ọ.
Ṣàwárí DIUTARONOMI 28:8
7
DIUTARONOMI 28:6
“Yóo bukun ọ nígbà tí o bá ń wọlé, yóo sì tún bukun ọ nígbà tí o bá ń jáde.
Ṣàwárí DIUTARONOMI 28:6
8
DIUTARONOMI 28:3
“OLUWA yóo bukun ọ ní ààrin ìlú, yóo sì bukun oko rẹ.
Ṣàwárí DIUTARONOMI 28:3
9
DIUTARONOMI 28:4
“Yóo bukun àwọn ọmọ rẹ, ati èso ilẹ̀ rẹ, ati àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ, ati àwọn ọmọ mààlúù rẹ, ati àwọn ọmọ aguntan rẹ.
Ṣàwárí DIUTARONOMI 28:4
10
DIUTARONOMI 28:9
“OLUWA yóo ṣe ọ́ ní eniyan rẹ̀, tí ó yà sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún ọ, bí o bá pa òfin rẹ̀ mọ́, tí o sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
Ṣàwárí DIUTARONOMI 28:9
11
DIUTARONOMI 28:5
“OLUWA yóo fi ibukun rẹ̀ sí orí ọkà rẹ, ati oúnjẹ rẹ.
Ṣàwárí DIUTARONOMI 28:5
12
DIUTARONOMI 28:11
OLUWA óo fún ọ ní ọpọlọpọ ọmọ, ati ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn. Àwọn igi eléso rẹ yóo máa so jìnwìnnì ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun rẹ búra fún àwọn baba rẹ, pé òun yóo fún ọ.
Ṣàwárí DIUTARONOMI 28:11
13
DIUTARONOMI 28:10
Gbogbo eniyan ayé ni yóo rí i pé orúkọ OLUWA ni wọ́n fi ń pè ọ́, wọn yóo sì máa bẹ̀rù rẹ.
Ṣàwárí DIUTARONOMI 28:10
14
DIUTARONOMI 28:14
tí o kò bá yipada ninu àwọn òfin tí mo ṣe fún ọ lónìí, tí o kò sì sá tọ àwọn oriṣa lọ, láti máa bọ wọ́n.
Ṣàwárí DIUTARONOMI 28:14
15
DIUTARONOMI 28:15
“Ṣugbọn bí o kò bá gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun rẹ, tí o kò sì pa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀ mọ́, bí mo ti fi lélẹ̀ fún ọ lónìí, gbogbo àwọn ègún wọnyi ni yóo ṣẹ sí orí rẹ tí yóo sì mọ́ ọ.
Ṣàwárí DIUTARONOMI 28:15
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò