1
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 5:2
Yoruba Bible
Má fi ẹnu rẹ sọ ìsọkúsọ, má sì kánjú sọ̀rọ̀ níwájú Ọlọrun, nítorí Ọlọrun ń bẹ lọ́run ìwọ sì wà láyé, nítorí náà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ mọ níwọ̀n.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 5:2
2
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 5:19
Gbogbo ẹni tí Ọlọrun bá fún ní ọrọ̀ ati ohun ìní, ati agbára láti gbádùn wọn, ati láti gba ìpín rẹ̀ kí ó sì láyọ̀ ninu iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ẹ̀bùn Ọlọrun ni.
Ṣàwárí ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 5:19
3
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 5:10
Kò sí iye tó lè tẹ́ ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ owó lọ́rùn; bákan náà ni ẹni tí ó bá fẹ́ràn ọrọ̀, kò sí iye tí ó lè jẹ lérè tí yóo tẹ́ ẹ lọ́rùn. Asán ni èyí pẹlu.
Ṣàwárí ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 5:10
4
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 5:1
Ṣọ́ra, nígbà tí o bá lọ sí ilé Ọlọrun, ó sàn kí o lọ máa kẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀ ju pé kí o lọ máa rúbọ bí àwọn aṣiwèrè tí ń ṣe, tí wọn kò sì mọ̀ pé nǹkan burúkú ni àwọn ń ṣe.
Ṣàwárí ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 5:1
5
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 5:4
Bí o bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Ọlọrun, má fi falẹ̀, tètè san án, nítorí kò ní inú dídùn sí àwọn òmùgọ̀.
Ṣàwárí ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 5:4
6
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 5:5
Ó sàn kí o má jẹ́ ẹ̀jẹ́ rárá ju pé kí o jẹ́ ẹ̀jẹ́ kí o má mú un ṣẹ lọ.
Ṣàwárí ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 5:5
7
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 5:12
Oorun dídùn ni oorun alágbàṣe, kì báà yó, kì báà má yó; ṣugbọn ìrònú ọrọ̀ kì í jẹ́ kí ọlọ́rọ̀ sùn lóru.
Ṣàwárí ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 5:12
8
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 5:15
Bí eniyan ti wáyé níhòòhò láìmú nǹkankan lọ́wọ́ wá bẹ́ẹ̀ ni yóo pada, láìmú nǹkankan lọ́wọ́ lọ, bí èrè làálàá tí a ṣe láyé.
Ṣàwárí ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 5:15
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò