1
ẸKISODU 5:1
Yoruba Bible
Lẹ́yìn náà, Mose ati Aaroni lọ sọ́dọ̀ Farao, wọ́n sọ fún un pé, “OLUWA, Ọlọrun Israẹli sọ pé, ‘Jẹ́ kí àwọn eniyan mi lọ, kí wọ́n lè lọ ṣe àjọ̀dún kan fún mi ninu aṣálẹ̀.’ ”
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ẸKISODU 5:1
2
ẸKISODU 5:23
Nítorí pé, láti ìgbà tí mo ti lọ sí ọ̀dọ̀ Farao láti bá a sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ, ni ó ti ń ṣe àwọn eniyan wọnyi níbi, bẹ́ẹ̀ ni o kò sì gba àwọn eniyan rẹ sílẹ̀ rárá!”
Ṣàwárí ẸKISODU 5:23
3
ẸKISODU 5:22
Mose bá tún yipada sí OLUWA, ó ní, “OLUWA, kí ló dé tí o fi ṣe ibi sí àwọn eniyan wọnyi? Kí ló dé tí o fi rán mi sí wọn?
Ṣàwárí ẸKISODU 5:22
4
ẸKISODU 5:2
Ṣugbọn Farao dá wọn lóhùn pé, “Ta ni OLUWA yìí tí n óo fi fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, kí n sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ? N kò mọ OLUWA ọ̀hún, ati pé n kò tilẹ̀ lè gbà rárá pé kí àwọn ọmọ Israẹli lọ.”
Ṣàwárí ẸKISODU 5:2
5
ẸKISODU 5:8-9
Iye bíríkì tí wọn ń ṣe tẹ́lẹ̀ kò sì gbọdọ̀ dín; nítorí pé nígbà tí iṣẹ́ kò ká wọn lára ni wọ́n ṣe ń rí ààyè pariwo pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ rúbọ sí Ọlọrun wa.’ Ẹ fi iṣẹ́ kún iṣẹ́ wọn. Nígbà tí iṣẹ́ bá wọ̀ wọ́n lọ́rùn gan-an, bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ ń parọ́ fún wọn, wọn kò ní fetí sí i.”
Ṣàwárí ẸKISODU 5:8-9
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò