Ninu ìran náà, mo rí i tí ìjì kan ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá, pẹlu ìkùukùu ńlá tí ìmọ́lẹ̀ ńlá ati iná tí ń kọ mànàmànà yí ìjì náà ká, ààrin iná náà sì dàbí idẹ dídán tí ń kọ mànà. Láàrin iná yìí, mo rí àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin kan, wọ́n dàbí eniyan. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu wọn ní ojú mẹrin mẹrin ati ìyẹ́ mẹrin mẹrin. Ẹsẹ̀ wọn tọ́, àtẹ́lẹsẹ̀ wọn sì dàbí pátákò mààlúù, ó ń kọ mànà bíi idẹ. Wọ́n ní ọwọ́ eniyan lábẹ́ ìyẹ́ wọn mẹrẹẹrin, wọ́n ní ojú mẹ́rin ati ìyẹ́ mẹ́rin. Báyìí ni ojú àwọn mẹrẹẹrin ati ìyẹ́ wọn rí: Ìyẹ́ wọn ń kan ara wọn; bí wọ́n bá ń rìn, olukuluku wọn á máa lọ siwaju tààrà, láìyà sí ibikíbi, bí wọn tí ń lọ.