Ó bá súre fún Josẹfu, ó ní,
“Kí Ọlọrun tí Abrahamu ati Isaaki, baba mi, ń sìn bukun àwọn ọmọ wọnyi,
kí Ọlọrun náà tí ó ti ń tọ́ mi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi títí di òní yìí bukun wọn,
kí angẹli tí ó yọ mí ninu gbogbo ewu bukun wọn;
kí ìrántí orúkọ mi, ati ti Abrahamu, ati ti Isaaki, àwọn baba mi, wà ní ìran wọn títí ayé,
kí atọmọdọmọ wọn pọ̀ lórí ilẹ̀ ayé.”