1
AISAYA 30:21
Yoruba Bible
Bí ẹ bá fẹ́ yapa sí apá ọ̀tún tabi apá òsì, ẹ óo máa gbọ́ ohùn kan lẹ́yìn yín tí yóo máa wí pé, “Ọ̀nà nìyí, ibí ni kí ẹ gbà.”
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí AISAYA 30:21
2
AISAYA 30:18
Nítorí náà OLUWA ń dúró dè yín, ó ti ṣetán láti ṣàánú yín. Yóo dìde, yóo sì ràn yín lọ́wọ́. Nítorí Ọlọrun Olódodo ni OLUWA.
Ṣàwárí AISAYA 30:18
3
AISAYA 30:15
Nítorí OLUWA Ọlọrun, Ẹni Mímọ́ Israẹli ní: “Bí ẹ bá yipada, tí ẹ sì farabalẹ̀, ẹ óo rí ìgbàlà; bí ẹ bá dákẹ́ jẹ́ẹ́ tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun, ẹ óo lágbára. Ṣugbọn ẹ kọ̀.
Ṣàwárí AISAYA 30:15
4
AISAYA 30:20
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA yóo jẹ́ kí ẹ ní ọpọlọpọ ìṣòro, yóo sì jẹ́ kí ẹ ṣe ọpọlọpọ wahala, sibẹsibẹ olùkọ́ yín kò ní farapamọ́ fun yín mọ́, ṣugbọn ẹ óo máa fi ojú yín rí i.
Ṣàwárí AISAYA 30:20
5
AISAYA 30:19
Ẹ̀yin ará Sioni tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, ẹ kò ní sọkún mọ́. OLUWA yóo ṣàánú yín nígbà tí ẹ bá ké pè é, yóo sì da yín lóhùn nígbà tí ó bá gbọ́ igbe yín.
Ṣàwárí AISAYA 30:19
6
AISAYA 30:1
OLUWA ní: “Àwọn ọmọ aláìgbọràn gbé. Àwọn tí wọn ń dá àbá tí ó yàtọ̀ sí tèmi, tí wọn ń kó ẹgbẹ́ jọ, ṣugbọn tí kìí ṣe nípa ẹ̀mí mi; kí wọ́n lè máa dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀.
Ṣàwárí AISAYA 30:1
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò