1
AISAYA 35:10
Yoruba Bible
Àwọn tí OLUWA rà pada yóo pada, wọn óo wá sí Sioni pẹlu orin, ayọ̀ ayérayé yóo kún inú wọn. Wọn óo rí ayọ̀ ati ìdùnnú gbà ìbànújẹ́ ati òṣé yóo sá kúrò níbẹ̀.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí AISAYA 35:10
2
AISAYA 35:3-4
Ẹ gbé ọwọ́ tí kò lágbára ró. Ẹ fún orúnkún tí kò lágbára ní okun. Ẹ sọ fún àwọn tí àyà wọn ń já pé: “Ẹ ṣe ara gírí, ẹ má bẹ̀rù. Ẹ wò ó! Ọlọrun yín óo wá pẹlu ẹ̀san, ó ń bọ̀ wá gbẹ̀san gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun; ó ń bọ̀ wá gbà yín là.”
Ṣàwárí AISAYA 35:3-4
3
AISAYA 35:8
Òpópónà kan yóo wà níbẹ̀, a óo máa pè é ní Ọ̀nà Ìwà Mímọ́; nǹkan aláìmọ́ kan kò ní gba ibẹ̀ kọjá, àwọn aláìgbọ́n kò sì ní dẹ́ṣẹ̀ níbẹ̀.
Ṣàwárí AISAYA 35:8
4
AISAYA 35:5
Ojú afọ́jú yóo là nígbà náà, etí adití yóo sì ṣí
Ṣàwárí AISAYA 35:5
5
AISAYA 35:6
arọ yóo máa fò bí ìgalà, odi yóo sì máa kọ orin ayọ̀. Nítorí odò ńlá yóo ṣàn jáde ninu aginjù àwọn odò kéékèèké yóo máa ṣàn ninu aṣálẹ̀.
Ṣàwárí AISAYA 35:6
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò