1
JEREMAYA 13:23
Yoruba Bible
Ṣé ó ṣeéṣe kí ará Kuṣi yí àwọ̀ ara rẹ̀ pada? Àbí kí àmọ̀tẹ́kùn fọ tóótòòtóó ara rẹ̀ dànù? Bí ó bá ṣeéṣe, á jẹ́ wí pé ẹ̀yin náà lè hùwà rere; ẹ̀yin tí ibi ṣíṣe ti mọ́ lára.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí JEREMAYA 13:23
2
JEREMAYA 13:16
Ẹ fi ògo fún OLUWA Ọlọrun yín kí ó tó mú òkùnkùn ṣú. Kí ẹ tó bẹ̀rẹ̀ sí fẹsẹ̀ kọ lórí òkè, níbi tí kò sí ìmọ́lẹ̀. Nígbà tí ẹ bá ń wá ìmọ́lẹ̀, yóo sọ ọ́ di ìṣúdudu, yóo sọ ọ́ di òkùnkùn biribiri.
Ṣàwárí JEREMAYA 13:16
3
JEREMAYA 13:10
Àwọn ẹni ibi wọnyi, tí wọ́n kọ̀, tí wọn kò gbọ́ tèmi, tí wọn ń fi oríkunkun tẹ̀lé ìfẹ́ ọkàn wọn, tí wọ́n sì ti sá tọ àwọn oriṣa lọ, tí wọn ń sìn wọ́n, tí wọn sì ń bọ wọ́n. Wọn yóo dàbí aṣọ yìí tí kò wúlò fún ohunkohun.
Ṣàwárí JEREMAYA 13:10
4
JEREMAYA 13:15
Ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ gbọ́, ẹ má gbéraga nítorí pé OLUWA ló sọ̀rọ̀.
Ṣàwárí JEREMAYA 13:15
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò