1
LUKU 10:19
Yoruba Bible
Mo fun yín ní àṣẹ láti tẹ ejò ati àkeekèé mọ́lẹ̀. Mo tún fun yín ní àṣẹ lórí gbogbo agbára ọ̀tá. Kò sí ohunkohun tí yóo pa yín lára.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí LUKU 10:19
2
LUKU 10:41-42
Ṣugbọn Oluwa dá a lóhùn pé, “Mata! Mata! Ò ń ṣe aájò, o sì ń dààmú nípa ohun pupọ. Ṣugbọn ẹyọ nǹkankan ni ó jẹ́ koṣeemani. Maria ti yan ipò tí ó dára tí a kò ní gbà kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.”
Ṣàwárí LUKU 10:41-42
3
LUKU 10:27
Ó dáhùn pé, “Kí ìwọ fẹ́ràn Oluwa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, ati pẹlu gbogbo ẹ̀mí rẹ, ati pẹlu gbogbo agbára rẹ ati pẹlu gbogbo òye rẹ; sì fẹ́ràn ọmọnikeji rẹ bí ara rẹ.”
Ṣàwárí LUKU 10:27
4
LUKU 10:2
Ó sọ fún wọn pé, “Àwọn nǹkan tí ó tó kórè pọ̀ ninu oko, ṣugbọn àwọn òṣìṣẹ́ kò pọ̀ tó. Nítorí náà, ẹ bẹ Oluwa ìkórè kí ó rán àwọn alágbàṣe sí ibi ìkórè rẹ̀.
Ṣàwárí LUKU 10:2
5
LUKU 10:36-37
“Ninu àwọn mẹta yìí, ta ni o rò pé ó jẹ́ ọmọnikeji ẹni tí ó bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà?” Amòfin náà dáhùn pé, “Ẹni tí ó ṣàánú fún un ni.” Jesu sọ fún un pé, “Ìwọ náà lọ ṣe bẹ́ẹ̀ gan-an.”
Ṣàwárí LUKU 10:36-37
6
LUKU 10:3
Ẹ máa lọ. Mo ran yín lọ bí aguntan sí ààrin ìkookò.
Ṣàwárí LUKU 10:3
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò