1
MAKU 11:24
Yoruba Bible
Nítorí èyí, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé, ohun gbogbo tí ẹ bá bèèrè ninu adura, ẹ gbàgbọ́ pé ẹ ti rí i gbà, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fun yín.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí MAKU 11:24
2
MAKU 11:23
mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, bí ẹnikẹ́ni bá wí fún òkè yìí pé, ‘ṣídìí kúrò níbi tí o wà, kí o bọ́ sí inú òkun,’ tí kò bá ṣiyèméjì, ṣugbọn tí ó gbàgbọ́ pé, ohun tí òun wí yóo rí bẹ́ẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún un.
Ṣàwárí MAKU 11:23
3
MAKU 11:25
Nígbà tí ẹ bá dìde dúró láti gbadura, ẹ dáríjì ẹnikẹ́ni tí ẹ bá ní ohunkohun ninu sí, kí Baba yín ọ̀run lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín. [
Ṣàwárí MAKU 11:25
4
MAKU 11:22
Jesu dáhùn, ó wí fún wọn pé, “Ẹ ní igbagbọ ninu Ọlọrun
Ṣàwárí MAKU 11:22
5
MAKU 11:17
Ó ń kọ́ wọn pé, “Kò ha wà ninu àkọsílẹ̀ pé, ‘Ilé adura fún gbogbo orílẹ̀-èdè ni a óo máa pe ilé mi?’ Ṣugbọn ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibi tí àwọn ọlọ́ṣà ń sápamọ́ sí!”
Ṣàwárí MAKU 11:17
6
MAKU 11:9
Àwọn tí ó ń lọ ní iwájú ati àwọn tí ó ń bọ̀ ní ẹ̀yìn ń kígbe pé, “Hosana! Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ ní orúkọ Oluwa.
Ṣàwárí MAKU 11:9
7
MAKU 11:10
Ibukun ni ìjọba tí ń bọ̀, ìjọba Dafidi baba ńlá wa. Hosana ní òkè ọ̀run!”
Ṣàwárí MAKU 11:10
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò