1
MAKU 2:17
Yoruba Bible
Nígbà tí Jesu gbọ́, ó wí fún wọn pé, “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn bíkòṣe àwọn tí ara wọn kò dá: èmi kò wá láti pe àwọn olódodo bíkòṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí MAKU 2:17
2
MAKU 2:5
Nígbà tí Jesu rí igbagbọ wọn, ó wí fún arọ náà pé, “Ọmọ, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”
Ṣàwárí MAKU 2:5
3
MAKU 2:27
Ó wá wí fún wọn pé, “Lílò eniyan ni a dá Ọjọ́ Ìsinmi fún, a kò dá eniyan fún Ọjọ́ Ìsinmi.
Ṣàwárí MAKU 2:27
4
MAKU 2:4
Nígbà tí wọn kò lè gbé e dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ nítorí ọ̀pọ̀ eniyan, wọ́n dá òrùlé lu ní ọ̀kánkán ibi tí Jesu wà. Nígbà tí wọ́n ti dá a lu tán, wọ́n sọ ọkunrin arọ náà kalẹ̀ ti òun ti ibùsùn rẹ̀.
Ṣàwárí MAKU 2:4
5
MAKU 2:10-11
Ṣugbọn kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ-Eniyan ní àṣẹ ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni,” ó bá wí fún arọ náà pé, “Mo wí fún ọ, dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o máa lọ sí ilé rẹ.”
Ṣàwárí MAKU 2:10-11
6
MAKU 2:9
Èwo ni ó rọrùn jù: Láti wí fún arọ náà pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ tabi láti wí pé, ‘Dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o máa rìn?’
Ṣàwárí MAKU 2:9
7
MAKU 2:12
Ọkunrin náà bá dìde lẹsẹkẹsẹ, ó gbé ibùsùn rẹ̀, ó bá jáde lọ lójú gbogbo wọn. Ẹnu ya gbogbo wọn, wọ́n sì ń yin Ọlọrun, wọ́n ní, “A kò rí èyí rí.”
Ṣàwárí MAKU 2:12
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò