1
MAKU 4:39-40
Yoruba Bible
Ó bá dìde lójú oorun, ó bá afẹ́fẹ́ wí, ó wí fún òkun pé, “Pa rọ́rọ́.” Afẹ́fẹ́ bá rọlẹ̀. Ìdákẹ́rọ́rọ́ bá dé. Ó bá bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ṣe lójo bẹ́ẹ̀? Ẹ kò ì tíì ní igbagbọ sibẹ?”
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí MAKU 4:39-40
2
MAKU 4:41
Ẹ̀rù ńlá bà wọ́n. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bi ara wọn pé, “Ta ni èyí, tí afẹ́fẹ́ ati òkun ń gbọ́ràn sí lẹ́nu!”
Ṣàwárí MAKU 4:41
3
MAKU 4:38
Jesu wà ní ẹ̀yìn ọkọ̀, ó fi ìrọ̀rí kan rọrí, ó bá sùn lọ. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ jí i, wọ́n ní, “Olùkọ́ni, o kò tilẹ̀ bìkítà bí a bá ṣègbé sinu omi!”
Ṣàwárí MAKU 4:38
4
MAKU 4:24
Ó tún wí fún wọn pé, “Ẹ fi ara balẹ̀ ro ohun tí ẹ bá gbọ́. Irú òfin tí ẹ bá fi ń ṣe ìdájọ́ fún eniyan ni a óo fi ṣe ìdájọ́ fún ẹ̀yin náà pẹlu èlé.
Ṣàwárí MAKU 4:24
5
MAKU 4:26-27
Ó tún wí pé, “Bí ìjọba Ọlọrun ti rí nìyí: ó dàbí ọkunrin kan tí ó gbin irúgbìn sí oko; ó ń sùn lálẹ́, ó ń jí ní òwúrọ̀, irúgbìn ń hù, ó ń dàgbà ní ọ̀nà tí ọkunrin náà kò mọ̀.
Ṣàwárí MAKU 4:26-27
6
MAKU 4:23
Bí ẹnikẹ́ni bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́.”
Ṣàwárí MAKU 4:23
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò