1
ÌWÉ ÒWE 13:20
Yoruba Bible
Bí eniyan bá ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóo gbọ́n, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń bá òmùgọ̀ kẹ́gbẹ́ yóo ṣìnà.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 13:20
2
ÌWÉ ÒWE 13:3
Ẹni tí ó ń ṣọ́ ẹnu rẹ̀, ẹ̀mí ara rẹ̀ ni ó ń ṣọ́, ẹni tí ń sọ̀rọ̀ àsọjù yóo parun.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 13:3
3
ÌWÉ ÒWE 13:24
Ẹni tí kì í bá na ọmọ rẹ̀ kò fẹ́ràn rẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ yóo máa bá a wí.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 13:24
4
ÌWÉ ÒWE 13:12
Bí ìrètí bá pẹ́ jù, a máa kó àárẹ̀ bá ọkàn, ṣugbọn kí á tètè rí ohun tí à ń fẹ́ a máa mú ara yá gágá.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 13:12
5
ÌWÉ ÒWE 13:6
Òdodo a máa dáàbò bo ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ bá tọ́, ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ a máa bi eniyan burúkú ṣubú.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 13:6
6
ÌWÉ ÒWE 13:11
Ọrọ̀ tí a fi ìkánjú kójọ kì í pẹ́ dínkù, ṣugbọn ẹni tí ó bá fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kó ọrọ̀ jọ yóo máa ní àníkún.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 13:11
7
ÌWÉ ÒWE 13:10
Ìjà ni ìgbéraga máa ń fà, ṣugbọn àwọn tí wọ́n bá gba ìmọ̀ràn yóo ní ọgbọ́n.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 13:10
8
ÌWÉ ÒWE 13:22
Eniyan rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń kó ọrọ̀ jọ fún àwọn olóòótọ́.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 13:22
9
ÌWÉ ÒWE 13:1
Ọlọ́gbọ́n ọmọ a máa gba ẹ̀kọ́ baba rẹ̀, ṣugbọn ẹlẹ́yà kì í gbọ́ ìbáwí.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 13:1
10
ÌWÉ ÒWE 13:18
Òṣì ati àbùkù ni yóo bá ẹni tí ó kọ ìmọ̀ràn, ṣugbọn ẹni tó bá gba ìbáwí yóo gba iyì.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 13:18
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò