1
ORIN DAFIDI 107:1
Yoruba Bible
Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun, nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 107:1
2
ORIN DAFIDI 107:20
Ó sọ̀rọ̀, ó sì mú wọn lára dá, ó tún kó wọn yọ ninu ìparun.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 107:20
3
ORIN DAFIDI 107:8-9
Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún àwọn ọmọ eniyan. Nítorí pé ó fi omi tẹ́ àwọn tí òùngbẹ ń gbẹ lọ́rùn, ó sì fi oúnjẹ dáradára bọ́ àwọn tí ebi ń pa ní àbọ́yó.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 107:8-9
4
ORIN DAFIDI 107:28-29
Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn, ó sì yọ wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn. Ó mú kí ìgbì dáwọ́ dúró, ó sì mú kí ríru omi òkun rọlẹ̀ wọ̀ọ̀.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 107:28-29
5
ORIN DAFIDI 107:6
Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn, ó sì yọ wọ́n kúrò ninu ìṣẹ́ wọn.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 107:6
6
ORIN DAFIDI 107:19
Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn, ó sì yọ wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 107:19
7
ORIN DAFIDI 107:13
Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn, ó sì gbà wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 107:13
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò