1
ORIN DAFIDI 37:4
Yoruba Bible
Jẹ́ kí inú rẹ máa dùn ninu OLUWA; yóo sì fún ọ ní ohun tí ọkàn rẹ ń fẹ́.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 37:4
2
ORIN DAFIDI 37:5
Fi ọ̀nà rẹ lé OLUWA lọ́wọ́; gbẹ́kẹ̀lé e, yóo sì ṣe ohun tí ó yẹ.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 37:5
3
ORIN DAFIDI 37:7
Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLUWA; fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé e. Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná nítorí ẹni tí nǹkan ń dára fún; tabi nítorí ẹni tí ń gbèrò ibi, tí ó sì ń ṣe é.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 37:7
4
ORIN DAFIDI 37:3
Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA; kí o sì máa ṣe rere. Máa gbe ilẹ̀ náà; ewu kò sì ní wu ọ́.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 37:3
5
ORIN DAFIDI 37:23-24
OLUWA níí darí ìgbésẹ̀ ẹni; a sì máa fi ẹsẹ̀ ẹni tí inú rẹ̀ bá dùn sí múlẹ̀. Bí ó tilẹ̀ ṣubú, kò ní lulẹ̀ lógèdèǹgbé, nítorí OLUWA yóo gbé e ró.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 37:23-24
6
ORIN DAFIDI 37:6
Yóo mú kí ìdáláre rẹ tàn bí ìmọ́lẹ̀; ẹ̀tọ́ rẹ yóo sì hàn kedere bí ọ̀sán gangan.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 37:6
7
ORIN DAFIDI 37:8
Yẹra fún ibinu; sì yàgò fún ìrúnú. Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná; ibi ni àyọrísí rẹ̀.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 37:8
8
ORIN DAFIDI 37:25
Mo ti jẹ́ ọmọde rí; mo sì ti dàgbà: n kò tíì ri kí á kọ olódodo sílẹ̀, tabi kí ọmọ rẹ̀ máa tọrọ jẹ.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 37:25
9
ORIN DAFIDI 37:1
Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná nítorí àwọn eniyan burúkú; má sì jowú àwọn aṣebi
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 37:1
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò