1
ÌFIHÀN 3:20
Yoruba Bible
Wò ó! Mo dúró ní ẹnu ọ̀nà, mò ń kan ìlẹ̀kùn. Bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ohùn mi, tí ó ṣílẹ̀kùn, n óo wọlé tọ̀ ọ́ lọ, n óo bá a jẹun, òun náà yóo sì bá mi jẹun.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ÌFIHÀN 3:20
2
ÌFIHÀN 3:15-16
Mo mọ iṣẹ́ rẹ. Mo mọ̀ pé o kò gbóná, bẹ́ẹ̀ ni o kò tutù. Ninu kí o gbóná tabi kí o tutù, ó yẹ kí o ṣe ọ̀kan. Nítorí pé o lọ́ wọ́ọ́rọ́wọ́ lásán, o kò gbóná, bẹ́ẹ̀ ni o kò tutù, n óo pọ̀ ọ́ jáde lẹ́nu mi.
Ṣàwárí ÌFIHÀN 3:15-16
3
ÌFIHÀN 3:19
Àwọn tí mo bá fẹ́ràn ni mò ń bá wí, àwọn ni mò ń tọ́ sọ́nà. Nítorí náà ní ìtara, kí o sì ronupiwada.
Ṣàwárí ÌFIHÀN 3:19
4
ÌFIHÀN 3:8
Mo mọ iṣẹ́ rẹ. Wò ó! Mo fi ìlẹ̀kùn kan tí ó ṣí sílẹ̀ siwaju rẹ, tí ẹnikẹ́ni kò lè tì. Mo mọ̀ pé agbára rẹ kéré, sibẹ o ti pa ọ̀rọ̀ mi mọ́. O kò sẹ́ orúkọ mi.
Ṣàwárí ÌFIHÀN 3:8
5
ÌFIHÀN 3:21
Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni n óo jẹ́ kí ó jókòó tì mí lórí ìtẹ́ mi, gẹ́gẹ́ bí Èmi náà ti ṣẹgun, tí mo jókòó ti baba mi lórí ìtẹ́ rẹ̀.
Ṣàwárí ÌFIHÀN 3:21
6
ÌFIHÀN 3:17
Nítorí ò ń sọ pé: Mo lówó, mo lọ́rọ̀. Kò sí ohun tí mo fẹ́ tí n kò ní. O kò mọ̀ pé akúṣẹ̀ẹ́ tí eniyan ń káàánú ni ọ́, òtòṣì afọ́jú tí ó wà ní ìhòòhò.
Ṣàwárí ÌFIHÀN 3:17
7
ÌFIHÀN 3:10
Nítorí o ti fi ìfaradà pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, Èmi náà yóo pa ọ́ mọ́ ní àkókò ìdánwò tí ń bọ̀ wá bá ayé, nígbà tí a óo dán gbogbo àwọn tí ó ń gbé inú ayé wò.
Ṣàwárí ÌFIHÀN 3:10
8
ÌFIHÀN 3:11
Mò ń bọ̀ kíákíá. Di ohun tí ń bẹ lọ́wọ́ rẹ mú ṣinṣin, kí ẹnikẹ́ni má baà gba adé rẹ.
Ṣàwárí ÌFIHÀN 3:11
9
ÌFIHÀN 3:2
Jí lójú oorun! Fún àwọn ohun tí ó ṣẹ́kù ní okun, nítorí àwọn náà ń kú lọ. Nítorí n kò rí iṣẹ́ kan tí o ṣe parí níwájú Ọlọrun mi.
Ṣàwárí ÌFIHÀN 3:2
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò