1
ROMU 14:17-18
Yoruba Bible
Nítorí ìjọba Ọlọrun kì í ṣe ọ̀ràn nǹkan jíjẹ ati nǹkan mímu, ọ̀ràn òdodo, alaafia ati ayọ̀ ninu Ẹ̀mí Mímọ́ ni. Ẹni tí ó bá ń sin Kristi báyìí jẹ́ ẹni tí inú Ọlọrun dùn sí, tí àwọn eniyan sì gbà fún.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ROMU 14:17-18
2
ROMU 14:8
Bí a bá wà láàyè, Oluwa ni a wà láàyè fún. Bí a bá sì kú, Oluwa ni a kú fún. Nítorí náà, ààyè wa ni o, òkú wa ni o, ti Oluwa ni wá.
Ṣàwárí ROMU 14:8
3
ROMU 14:19
Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á máa lépa àwọn nǹkan tí ń mú alaafia wá, ati àwọn nǹkan tí yóo yọrí sí ìdàgbàsókè láàrin ara wa.
Ṣàwárí ROMU 14:19
4
ROMU 14:13
Ẹ má ṣe jẹ́ kí á máa dá ara wa lẹ́jọ́ mọ́. Ìpinnu kan tí à bá ṣe ni pé, kí á má ṣe fi ohun ìkọsẹ̀ kan, tabi ohunkohun tí yóo ṣi arakunrin wa lọ́nà, sí ojú ọ̀nà rẹ̀.
Ṣàwárí ROMU 14:13
5
ROMU 14:11-12
Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Oluwa fi ara rẹ̀ búra, ó ní, ‘Èmi ni gbogbo orúnkún yóo kúnlẹ̀ fún, Èmi ni gbogbo ẹnu yóo pè ní Ọlọrun.’ ” Nítorí náà, olukuluku wa ni yóo sọ ti ẹnu ara rẹ̀ níwájú Ọlọrun.
Ṣàwárí ROMU 14:11-12
6
ROMU 14:1
Ẹ fa àwọn tí igbagbọ wọn kò tíì fẹsẹ̀ múlẹ̀ mọ́ra, kì í ṣe láti máa bá wọn jiyàn lórí ohun tí kò tó iyàn.
Ṣàwárí ROMU 14:1
7
ROMU 14:4
Ta ni ìwọ tí ò ń dá ọmọ-ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn lẹ́jọ́? Kì báà dúró, kì báà sì ṣubú, ọ̀gá rẹ̀ nìkan ni ìdájọ́ tọ́ sí. Yóo tilẹ̀ dúró ni, nítorí Oluwa lè gbé e ró.
Ṣàwárí ROMU 14:4
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò