1
I. Kor 3:16
Bibeli Mimọ
Ẹnyin kò mọ̀ pe tẹmpili Ọlọrun li ẹnyin iṣe, ati pe Ẹmí Ọlọrun ngbe inu nyin?
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí I. Kor 3:16
2
I. Kor 3:11
Nitori ipilẹ miran ni ẹnikan kò le fi lelẹ jù eyiti a ti fi lelẹ lọ, ti iṣe Jesu Kristi.
Ṣàwárí I. Kor 3:11
3
I. Kor 3:7
Njẹ kì iṣe ẹniti o ngbìn nkankan, bẹ̃ni kì iṣe ẹniti mbomirin; bikoṣe Ọlọrun ti o nmu ibisi wá.
Ṣàwárí I. Kor 3:7
4
I. Kor 3:9
Nitori alabaṣiṣẹpọ pẹlu Ọlọrun li awa: ọgbà Ọlọrun ni nyin, ile Ọlọrun ni nyin.
Ṣàwárí I. Kor 3:9
5
I. Kor 3:13
Iṣẹ́ olukuluku enia yio hàn. Nitori ọjọ na yio fi i hàn, nitoripe ninu iná li a o fi i hàn; iná na yio si dán iṣẹ olukuluku wò irú eyiti iṣe.
Ṣàwárí I. Kor 3:13
6
I. Kor 3:8
Njẹ ẹniti ngbìn, ati ẹniti mbomirin, ọkan ni nwọn jasi: olukuluku yio si gba ère tirẹ̀ gẹgẹ bi iṣẹ tirẹ̀.
Ṣàwárí I. Kor 3:8
7
I. Kor 3:18
Ki ẹnikẹni máṣe tàn ara rẹ̀ jẹ. Bi ẹnikẹni ninu nyin laiye yi ba rò pe on gbọ́n, ẹ jẹ ki o di aṣiwere, ki o le ba gbọ́n.
Ṣàwárí I. Kor 3:18
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò