1
I. A. Ọba 18:37
Bibeli Mimọ
Gbọ́ ti emi, Oluwa, gbọ́ ti emi, ki awọn enia yi ki o le mọ̀ pe, Iwọ Oluwa li Ọlọrun, ati pe, Iwọ tún yi ọkàn wọn pada.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí I. A. Ọba 18:37
2
I. A. Ọba 18:36
O si ṣe, ni irubọ aṣalẹ, ni Elijah woli sunmọ tòsi, o si wipe, Oluwa Ọlọrun Abrahamu, Isaaki, ati Israeli, jẹ ki o di mimọ̀ loni pe, iwọ li Ọlọrun ni Israeli, emi si ni iranṣẹ rẹ, ati pe mo ṣe gbogbo nkan wọnyi nipa ọ̀rọ rẹ.
Ṣàwárí I. A. Ọba 18:36
3
I. A. Ọba 18:21
Elijah si tọ gbogbo awọn enia na wá, o si wipe, Yio ti pẹ to ti ẹnyin o ma ṣiyemeji? Bi Oluwa ba ni Ọlọrun, ẹ mã tọ̀ ọ lẹhin: ṣugbọn bi Baali ba ni ẹ mã tọ̀ ọ lẹhin! Awọn enia na kò si da a li ohùn ọ̀rọ kan.
Ṣàwárí I. A. Ọba 18:21
4
I. A. Ọba 18:38
Nigbana ni iná Oluwa bọ́ silẹ, o si sun ẹbọsisun na ati igi, ati okuta wọnnì, ati erupẹ o si lá omi ti mbẹ ninu yàra na.
Ṣàwárí I. A. Ọba 18:38
5
I. A. Ọba 18:39
Nigbati gbogbo awọn enia ri i, nwọn da oju wọn bolẹ: nwọn si wipe, Oluwa, on li Ọlọrun; Oluwa, on li Ọlọrun!
Ṣàwárí I. A. Ọba 18:39
6
I. A. Ọba 18:44
O si ṣe, ni igba keje, o si wipe, Kiyesi i, awọsanmọ kekere kan dide lati inu okun, gẹgẹ bi ọwọ́ enia. On si wipe, Goke lọ, wi fun Ahabu pe, Di kẹkẹ́ rẹ, ki o si sọkalẹ, ki òjo ki o má ba da ọ duro.
Ṣàwárí I. A. Ọba 18:44
7
I. A. Ọba 18:46
Ọwọ́ Oluwa si mbẹ lara Elijah: o si di amure ẹ̀gbẹ rẹ̀, o si sare niwaju Ahabu titi de Jesreeli.
Ṣàwárí I. A. Ọba 18:46
8
I. A. Ọba 18:41
Elijah si wi fun Ahabu pe, Goke lọ, jẹ, ki o si mu; nitori iró ọ̀pọlọpọ òjo mbẹ.
Ṣàwárí I. A. Ọba 18:41
9
I. A. Ọba 18:43
O si wi fun ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Goke lọ nisisiyi, ki o si wò iha okun. On si goke lọ, o si wò, o si wipe, Kò si nkan. O si wipe, Tun lọ nigba meje.
Ṣàwárí I. A. Ọba 18:43
10
I. A. Ọba 18:30
Njẹ Elijah wi fun gbogbo awọn enia na pe, Ẹ sunmọ mi. Gbogbo awọn enia na si sunmọ ọ. On si tun pẹpẹ Oluwa ti o ti wo lulẹ ṣe.
Ṣàwárí I. A. Ọba 18:30
11
I. A. Ọba 18:24
Ki ẹ si kepe orukọ awọn ọlọrun nyin, emi o si kepè orukọ Oluwa: Ọlọrun na ti o ba fi iná dahùn on na li Ọlọrun. Gbogbo awọn enia na si dahùn, nwọn si wipe, O wi i re.
Ṣàwárí I. A. Ọba 18:24
12
I. A. Ọba 18:31
Elijah si mu okuta mejila, gẹgẹ bi iye ẹ̀ya ọmọ Jakobu, ẹniti ọ̀rọ Oluwa tọ̀ wá, wipe, Israeli li orukọ rẹ yio ma jẹ
Ṣàwárí I. A. Ọba 18:31
13
I. A. Ọba 18:27
O si ṣe, li ọ̀sangangan ni Elijah fi wọn ṣe ẹlẹya o si wipe, Ẹ kigbe lohùn rara, ọlọrun sa li on; bọya o nṣe àṣaro, tabi on nlepa, tabi o re àjo, bọya o sùn, o yẹ ki a ji i.
Ṣàwárí I. A. Ọba 18:27
14
I. A. Ọba 18:32
Okuta wọnyi li o fi tẹ́ pẹpẹ kan li orukọ Oluwa, o si wà kòtò yi pẹpẹ na ka, ti o le gba iwọn oṣùwọn irugbin meji.
Ṣàwárí I. A. Ọba 18:32
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò