1
I. Pet 3:15-16
Bibeli Mimọ
Ṣugbọn ẹ bọ̀wọ fun Kristi bi Oluwa lọkan nyin: ki ẹ si mura tan nigbagbogbo lati dá olukuluku lohùn ti mbere ireti ti o mbẹ ninu nyin, ṣugbọn pẹlu ọkàn tutù ati ìbẹru. Ki ẹ mã ni ẹri-ọkàn rere, bi nwọn ti nsọ̀rọ nyin ni ibi, ki oju ki o le ti awọn ti nkẹgan iwa rere nyin ninu Kristi.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí I. Pet 3:15-16
2
I. Pet 3:12
Nitori oju Oluwa mbẹ lara awọn olododo, etí rẹ̀ si ṣí si ẹbẹ wọn: ṣugbọn oju Oluwa nwo awọn ti nṣe buburu.
Ṣàwárí I. Pet 3:12
3
I. Pet 3:3-4
Ọṣọ́ ẹniti ki o má jẹ ọṣọ́ ode, ti irun didì, ati ti wura lilo, tabi ti aṣọ wiwọ̀; Ṣugbọn ki o jẹ ti ẹniti o farasin li ọkàn, ninu ọ̀ṣọ́ aidibajẹ ti ẹmí irẹlẹ ati ẹmí tutù, eyiti iṣe iyebiye niwaju Ọlọrun.
Ṣàwárí I. Pet 3:3-4
4
I. Pet 3:10-11
Nitori, ẹniti yio ba fẹ ìye, ti yio si ri ọjọ rere, ki o pa ahọn rẹ̀ mọ́ kuro ninu ibi, ati ète rẹ̀ kuro ni sisọ ọrọ ẹ̀tan: Ki o yà kuro ninu ibi, ki o si mã ṣe rere; ki o mã wá alafia, ki o si mã lepa rẹ̀.
Ṣàwárí I. Pet 3:10-11
5
I. Pet 3:8-9
Lakotan, ki gbogbo nyin ṣe oninu kan, ẹ mã ba ará nyin kẹdun, ẹ ni ifẹ ará, ẹ mã ṣe ìyọnú, ẹ ni ẹmí irẹlẹ. Ẹ máṣe fi buburu san buburu, tabi fi ẽbú san ẽbú; ṣugbọn kàka bẹ̃, ẹ mã súre; nitori eyi li a pè nyin si, ki ẹnyin ki o le jogún ibukún.
Ṣàwárí I. Pet 3:8-9
6
I. Pet 3:13
Tani yio si ṣe nyin ni ibi, bi ẹnyin ba jẹ onítara si ohun rere?
Ṣàwárí I. Pet 3:13
7
I. Pet 3:11
Ki o yà kuro ninu ibi, ki o si mã ṣe rere; ki o mã wá alafia, ki o si mã lepa rẹ̀.
Ṣàwárí I. Pet 3:11
8
I. Pet 3:17
Nitori o san, bi o bá jẹ ifẹ Ọlọrun, ki ẹ jìya fun rere iṣe jù fun buburu iṣe lọ.
Ṣàwárí I. Pet 3:17
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò