1
Iṣe Apo 3:19
Bibeli Mimọ
Nitorina ẹ ronupiwada, ki ẹ si tun yipada, ki a le pa ẹ̀ṣẹ nyin rẹ́, ki akoko itura ba le ti iwaju Oluwa wá
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Iṣe Apo 3:19
2
Iṣe Apo 3:6
Peteru wipe, Fadakà ati wura emi kò ni; ṣugbọn ohun ti mo ni eyini ni mo fifun ọ: Li orukọ Jesu Kristi ti Nasareti, dide ki o si mã rin.
Ṣàwárí Iṣe Apo 3:6
3
Iṣe Apo 3:7-8
O si fà a li ọwọ́ ọtún, o si gbé e dide: li ojukanna ẹsẹ rẹ̀ ati egungun kokosẹ rẹ̀ si mokun. O si nfò soke, o duro, o si bẹrẹ si rin, o si ba wọn wọ̀ inu tẹmpili lọ, o nrìn, o si nfò, o si nyìn Ọlọrun.
Ṣàwárí Iṣe Apo 3:7-8
4
Iṣe Apo 3:16
Ati orukọ rẹ̀, nipa igbagbọ́ ninu orukọ rẹ̀, on li o mu ọkunrin yi lara le, ẹniti ẹnyin ri ti ẹ si mọ̀: ati igbagbọ́ nipa rẹ̀ li o fun u ni dida ara ṣáṣa yi li oju gbogbo nyin.
Ṣàwárí Iṣe Apo 3:16
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò