1
Deu 4:29
Bibeli Mimọ
Ṣugbọn bi iwọ ba wá OLUWA Ọlọrun rẹ lati ibẹ̀ lọ, iwọ o ri i, bi iwọ ba fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ wá a.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Deu 4:29
2
Deu 4:31
Nitoripe Ọlọrun alãnu ni OLUWA Ọlọrun rẹ; on ki yio kọ̀ ọ silẹ, bẹ̃ni ki yio run ọ, bẹ̃ni ki yio gbagbé majẹmu awọn baba rẹ, ti o ti bura fun wọn.
Ṣàwárí Deu 4:31
3
Deu 4:24
Nitori OLUWA Ọlọrun rẹ ajonirun iná ni, Ọlọrun owú.
Ṣàwárí Deu 4:24
4
Deu 4:9
Kìki ki iwọ ki o ma kiyesara rẹ, ki o si ṣọ́ ọkàn rẹ gidigidi, ki iwọ ki o má ba gbagbé ohun ti oju rẹ ti ri, ati ki nwọn ki o má ba lọ kuro li àiya rẹ li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo; ṣugbọn ki iwọ ki o ma fi wọn kọ́ awọn ọmọ rẹ, ati awọn ọmọ ọmọ rẹ
Ṣàwárí Deu 4:9
5
Deu 4:39
Nitorina ki iwọ ki o mọ̀ li oni, ki o si rò li ọkàn rẹ pe, OLUWA on li Ọlọrun loke ọrun, ati lori ilẹ nisalẹ: kò sí ẹlomiran.
Ṣàwárí Deu 4:39
6
Deu 4:7
Nitori orilẹ-ède nla wo li o wà, ti o ní Ọlọrun sunmọ wọn to, bi OLUWA Ọlọrun wa ti ri ninu ohun gbogbo ti awa kepè e si?
Ṣàwárí Deu 4:7
7
Deu 4:30
Nigbati iwọ ba mbẹ ninu ipọnju, ti nkan gbogbo wọnyi ba si bá ọ, nikẹhin ọjọ́, bi iwọ ba yipada si OLUWA Ọlọrun rẹ, ti iwọ ba si gbà ohùn rẹ̀ gbọ́
Ṣàwárí Deu 4:30
8
Deu 4:2
Ẹ kò gbọdọ fikún ọ̀rọ na ti mo palaṣẹ fun nyin, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ bù kuro ninu rẹ̀, ki ẹnyin ki o le pa ofin OLUWA Ọlọrun nyin mọ́, ti mo palaṣẹ fun nyin.
Ṣàwárí Deu 4:2
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò