1
Efe 6:12
Bibeli Mimọ
Nitoripe kì iṣe ẹ̀jẹ ati ẹran-ara li awa mba jijakadi, ṣugbọn awọn ijoye, awọn ọlọla, awọn alaṣẹ ibi òkunkun aiye yi, ati awọn ẹmí buburu ni oju ọrun.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Efe 6:12
2
Efe 6:18
Pẹlu gbogbo adura ati ẹbẹ ni ki ẹ mã gbadura nigbagbogbo ninu Ẹmí, ki ẹ si mã ṣọra si i ninu iduroṣinṣin gbogbo, ati ẹ̀bẹ fun gbogbo enia mimọ́
Ṣàwárí Efe 6:18
3
Efe 6:11
Ẹ gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀, ki ẹnyin ki o le kọ oju ija si arekereke Eṣu.
Ṣàwárí Efe 6:11
4
Efe 6:13
Nitorina ẹ gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀ ki ẹnyin ki o le duro tiri si ọjọ ibi, nigbati ẹnyin bá si ti ṣe ohun gbogbo tan, ki ẹ si duro.
Ṣàwárí Efe 6:13
5
Efe 6:16-17
Léke gbogbo rẹ̀, ẹ mu apata igbagbọ́, nipa eyiti ẹnyin ó le mã fi paná gbogbo ọfa iná ẹni ibi nì. Ki ẹ si mu aṣibori igbala, ati idà Ẹmí, ti iṣe ọ̀rọ Ọlọrun
Ṣàwárí Efe 6:16-17
6
Efe 6:14-15
Ẹ duro nitorina lẹhin ti ẹ ti fi àmure otitọ di ẹgbẹ nyin, ti ẹ si ti di ìgbaiya ododo nì mọra; Ti ẹ si ti fi imura ihinrere alafia wọ̀ ẹsẹ nyin ni bàta
Ṣàwárí Efe 6:14-15
7
Efe 6:10
Lakotan, ará mi, ẹ jẹ alagbara ninu Oluwa, ati ninu agbara ipá rẹ̀.
Ṣàwárí Efe 6:10
8
Efe 6:2-3
Bọ̀wọ fun baba ati iya rẹ (eyi ti iṣe ofin ikini pẹlu ileri), Ki o le dara fun ọ, ati ki iwọ ki o le wà pẹ li aiye.
Ṣàwárí Efe 6:2-3
9
Efe 6:1
ẸNYIN ọmọ, ẹ mã gbọ ti awọn õbi nyin ninu Oluwa: nitoripe eyi li o tọ́.
Ṣàwárí Efe 6:1
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò