1
Isa 35:10
Bibeli Mimọ
Awọn ẹni-iràpada Oluwa yio padà, nwọn o wá si Sioni ti awọn ti orin, ayọ̀ ainipẹkun yio si wà li ori wọn: nwọn o ri ayọ̀ ati inu didùn gbà, ikãnu on imí-ẹ̀dùn yio si fò lọ.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Isa 35:10
2
Isa 35:3-4
Ẹ mu ọwọ́ ailera le, ẹ si mu ẽkun ailera lokun. Ẹ sọ fun awọn alailaiyà pe, ẹ tujuka, ẹ má bẹ̀ru: wò o, Ọlọrun nyin o wá ti on ti ẹsan, Ọlọrun ti on ti igbẹsan; on o wá, yio si gbà nyin.
Ṣàwárí Isa 35:3-4
3
Isa 35:8
Opopo kan yio si wà nibẹ, ati ọ̀na kan, a o si ma pè e ni, Ọ̀na iwà-mimọ́; alaimọ́ kì yio kọja nibẹ; nitori on o wà pẹlu wọn: awọn èro ọ̀na na, bi nwọn tilẹ jẹ òpe, nwọn kì yio ṣì i.
Ṣàwárí Isa 35:8
4
Isa 35:5
Nigbana li oju awọn afọju yio là, eti awọn aditi yio si ṣi.
Ṣàwárí Isa 35:5
5
Isa 35:6
Nigbana li awọn arọ yio fò bi agbọ̀nrin, ati ahọ́n odi yio kọrin: nitori omi yio tú jade li aginju, ati iṣàn omi ni ijù.
Ṣàwárí Isa 35:6
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò