1
Isa 62:4
Bibeli Mimọ
A ki yio pè ọ ni Ikọ̀silẹ mọ́, bẹ̃ni a ki yio pè ilẹ rẹ ni Ahoro mọ: ṣugbọn a o pè ọ ni Hefsiba: ati ilẹ rẹ ni Beula: nitori inu Oluwa dùn si ọ, a o si gbe ilẹ rẹ ni iyawo.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Isa 62:4
2
Isa 62:6-7
Emi ti fi awọn alore sori odi rẹ, iwọ Jerusalemu, ti kì yio pa ẹnu wọn mọ lọsan ati loru titilai: ẹnyin ti nṣe iranti Oluwa, ẹ máṣe dakẹ. Ẹ máṣe fun u ni isimi, titi yio fi fi idi Jerusalemu mulẹ, ti yio ṣe e ni iyìn li aiye.
Ṣàwárí Isa 62:6-7
3
Isa 62:3
Iwọ o jẹ ade ogo pẹlu li ọwọ́ Oluwa, ati adé oyè ọba li ọwọ́ Ọlọrun rẹ.
Ṣàwárí Isa 62:3
4
Isa 62:5
Gẹgẹ bi ọdọmọkunrin ti igbé wundia ni iyawo, bẹ̃ni awọn ọmọ rẹ ọkunrin yio gbe ọ ni iyawo: ati bi ọkọ iyawo ti iyọ̀ si iyawo, bẹ̃ni Ọlọrun rẹ yio yọ̀ si ọ.
Ṣàwárí Isa 62:5
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò