1
Isa 65:24
Bibeli Mimọ
Yio si ṣe, pe, ki nwọn ki o to pè, emi o dahùn; ati bi nwọn ba ti nsọ̀rọ lọwọ, emi o gbọ́.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Isa 65:24
2
Isa 65:17
Sa wò o, emi o da ọrun titun ati aiye titun: a kì yio si ranti awọn ti iṣaju, bẹ̃ni nwọn kì yio wá si aiya.
Ṣàwárí Isa 65:17
3
Isa 65:23
Nwọn kì yio ṣiṣẹ lasan, nwọn kì yio bimọ fun wahala: nitori awọn ni iru alabukun Oluwa ati iru-ọmọ wọn pẹlu wọn.
Ṣàwárí Isa 65:23
4
Isa 65:22
Nwọn kì yio kọ ile fun ẹlomiran lati gbé, nwọn kì yio gbìn fun ẹlomiran lati jẹ: nitori gẹgẹ bi ọjọ igi li ọjọ awọn enia mi ri, awọn ayanfẹ mi yio si jìfà iṣẹ ọwọ́ wọn.
Ṣàwárí Isa 65:22
5
Isa 65:20
Ki yio si ọmọ-ọwọ nibẹ ti ọjọ rẹ̀ kì yio pẹ́, tabi àgba kan ti ọjọ rẹ̀ kò kún: nitori ọmọde yio kú li ọgọrun ọdun; ṣugbọn ẹlẹṣẹ ọlọgọrun ọdun yio di ẹni-ifibu.
Ṣàwárí Isa 65:20
6
Isa 65:25
Ikõko ati ọdọ-agutan yio jumọ jẹ pọ̀, kiniun yio si jẹ koriko bi akọ-mãlu: erupẹ ni yio jẹ onjẹ ejò. Nwọn kì yio panilara, tabi ki nwọn panirun ni gbogbo oke mimọ́ mi, li Oluwa wi.
Ṣàwárí Isa 65:25
7
Isa 65:19
Emi o si ṣe ariya ni Jerusalemu, emi o si yọ̀ ninu awọn enia mi: a kì yio si tun gbọ́ ohùn ẹkún mọ ninu rẹ̀, tabi ohùn igbe.
Ṣàwárí Isa 65:19
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò