1
Joh 14:27
Bibeli Mimọ
Alafia ni mo fi silẹ fun nyin, alafia mi ni mo fifun nyin: kì iṣe gẹgẹ bi aiye iti fi funni li emi fifun nyin. Ẹ máṣe jẹ ki okàn nyin daru, ẹ má si jẹ ki o warìri.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Joh 14:27
2
Joh 14:6
Jesu wi fun u pe, Emi li ọ̀na, ati otitọ, ati iye: kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ Baba, bikoṣe nipasẹ mi.
Ṣàwárí Joh 14:6
3
Joh 14:1
Ẹ maṣe jẹ ki ọkàn nyin dàru: ẹ gbà Ọlọrun gbọ́, ẹ gbà mi gbọ́ pẹlu.
Ṣàwárí Joh 14:1
4
Joh 14:26
Ṣugbọn Olutunu na, Ẹmí Mimọ́, ẹniti Baba yio rán li orukọ mi, on ni yio kọ́ nyin li ohun gbogbo, yio si rán nyin leti ohun gbogbo ti mo ti sọ fun nyin.
Ṣàwárí Joh 14:26
5
Joh 14:21
Ẹniti o ba li ofin mi, ti o ba si npa wọn mọ́, on li ẹniti ọ fẹràn mi: ẹniti o ba si fẹràn mi, a o fẹrán rẹ̀ lati ọdọ Baba mi wá, emi o si fẹràn rẹ̀, emi o si fi ara mi hàn fun u.
Ṣàwárí Joh 14:21
6
Joh 14:16-17
Emi ó si bère lọwọ Baba, on ó si fun nyin li Olutunu miran, ki o le mã ba nyin gbé titi lailai, Ani Ẹmí otitọ nì; ẹniti araiye kò le gbà, nitoriti kò ri i, bẹ̃ni kò si mọ̀ ọ: ṣugbọn ẹnyin mọ̀ ọ; nitoriti o mba nyin gbe, yio si wà ninu nyin.
Ṣàwárí Joh 14:16-17
7
Joh 14:13-14
Ohunkohun ti ẹnyin ba si bère li orukọ mi, on na li emi ó ṣe, ki a le yìn Baba logo ninu Ọmọ. Bi ẹnyin ba bère ohunkohun li orukọ mi, emi ó ṣe e.
Ṣàwárí Joh 14:13-14
8
Joh 14:15
Bi ẹnyin ba fẹran mi, ẹ ó pa ofin mi mọ́.
Ṣàwárí Joh 14:15
9
Joh 14:2
Ninu ile Baba mi ọ̀pọlọpọ ibugbe li o wà: ibamáṣe bẹ̃, emi iba ti sọ fun nyin. Nitori emi nlọ ipèse àye silẹ fun nyin.
Ṣàwárí Joh 14:2
10
Joh 14:3
Bi mo ba si lọ ipèse àye silẹ fun nyin, emi o tún pada wá, emi o si mu nyin lọ sọdọ emi tikarami; pe nibiti emi gbé wà, ki ẹnyin le wà nibẹ pẹlu.
Ṣàwárí Joh 14:3
11
Joh 14:5
Tomasi wi fun u pe, Oluwa, a kò mọ̀ ibiti o gbe nlọ; a o ha ti ṣe mọ̀ ọ̀na na?
Ṣàwárí Joh 14:5
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò