1
Mat 15:18-19
Bibeli Mimọ
Ṣugbọn nkan wọnni ti o ti ẹnu jade, inu ọkàn li o ti wá; nwọn a si sọ enia di alaimọ́. Nitori lati inu ọkàn ni iro buburu ti ijade wá, ipania, panṣaga, àgbere, olè, ẹ̀rí èké ati ọ̀rọ buburu
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Mat 15:18-19
2
Mat 15:11
Ki iṣe ohun ti o wọni li ẹnu lọ, ni isọ enia di alaimọ́; bikoṣe eyi ti o ti ẹnu jade wá, eyini ni isọ enia di alaimọ́.
Ṣàwárí Mat 15:11
3
Mat 15:8-9
Awọn enia yi nfi ẹnu wọn sunmọ mi, nwọn si nfi ète wọn bọla fun mi; ṣugbọn ọkàn wọn jìna si mi. Ṣugbọn lasan ni nwọn ntẹriba fun mi, nwọn nfi ofin enia kọ́ni fun ẹkọ.
Ṣàwárí Mat 15:8-9
4
Mat 15:28
Nigbana ni Jesu dahùn o si wi fun u pe, Obinrin yi, igbagbọ́ nla ni tirẹ: ki o ri fun ọ gẹgẹ bi iwọ ti nfẹ. A si mu ọmọbinrin rẹ̀ larada ni wakati kanna.
Ṣàwárí Mat 15:28
5
Mat 15:25-27
Nigbana li o wá, o si tẹriba fun u, wipe, Oluwa, ràn mi lọwọ. Ṣugbọn o dahùn, wipe, Ko tọ́ ki a mu akara awọn ọmọ, ki a fi i fun ajá. O si wipe, Bẹni, Oluwa: awọn ajá a ma jẹ ninu ẹrún ti o ti ori tabili oluwa wọn bọ́ silẹ.
Ṣàwárí Mat 15:25-27
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò