1
Mak 13:13
Bibeli Mimọ
Gbogbo enia ni yio si korira nyin nitori orukọ mi: ṣugbọn ẹniti o ba foritì i titi fi de opin, on na li a o gbalà.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Mak 13:13
2
Mak 13:33
Ẹ mã ṣọra, ki ẹ si mã gbadura: nitori ẹnyin ko mọ̀ igbati akokò na yio de.
Ṣàwárí Mak 13:33
3
Mak 13:11
Ṣugbọn nigbati nwọn ba nfà nyin, lọ, ti nwọn ba si nfi nyin le wọn lọwọ, ẹ maṣe ṣaniyan ṣaju ohun ti ẹ o sọ; ṣugbọn ohun ti a ba fifun nyin ni wakati na, on ni ki ẹnyin ki o wi: nitori kì iṣe ẹnyin ni nwi, bikoṣe Ẹmí Mimọ́.
Ṣàwárí Mak 13:11
4
Mak 13:31
Ọrun on aiye yio rekọja: ṣugbọn ọ̀rọ mi kì yio rekọja.
Ṣàwárí Mak 13:31
5
Mak 13:32
Ṣugbọn niti ọjọ ati wakati na, kò si ẹnikan ti o mọ̀ ọ, kò si, ki tilẹ iṣe awọn angẹli ọrun, tabi Ọmọ, bikoṣe Baba mi nikanṣoṣo.
Ṣàwárí Mak 13:32
6
Mak 13:7
Nigbati ẹnyin ba si ngburó ogun ati idagìri ogun; ki ẹnyin ki o máṣe jaiya: nitori irú nkan wọnyi kò le ṣe ki o ma ṣẹ; ṣugbọn opin na kì iṣe isisiyi.
Ṣàwárí Mak 13:7
7
Mak 13:35-37
Nitorina ẹ mã ṣọna: nitori ẹnyin ko mọ̀ igba ti bãle ile mbọ̀wá, bi li alẹ ni, tabi larin ọganjọ, tabi li akukọ, tabi li owurọ̀: Pe, nigbati o ba de li ojijì, ki o máṣe ba nyin li oju orun. Ohun ti mo wi fun nyin, mo wi fun gbogbo enia, Ẹ mã ṣọna.
Ṣàwárí Mak 13:35-37
8
Mak 13:8
Nitoripe orilẹ-ède yio dide si orilẹ-ede, ati ilẹ-ọba si ilẹ-ọba: isẹlẹ yio si wà ni ibi pupọ, ìyan yio si wà ati wahalà: nkan wọnyi ni ipilẹṣẹ ipọnju.
Ṣàwárí Mak 13:8
9
Mak 13:10
A kò le ṣaima kọ́ wasu ihinrere ni gbogbo orilẹ-ède.
Ṣàwárí Mak 13:10
10
Mak 13:6
Nitori awọn enia pipọ yio wá li orukọ mi, wipe, Emi ni Kristi; nwọn o si tàn ọ̀pọlọpọ jẹ.
Ṣàwárí Mak 13:6
11
Mak 13:9
Ṣugbọn ẹ mã kiyesara nyin: nitori nwọn ó si fi nyin le awọn igbimọ lọwọ; a o si lù nyin ninu sinagogu: a o si mu nyin duro niwaju awọn balẹ ati awọn ọba nitori orukọ mi, fun ẹrí si wọn.
Ṣàwárí Mak 13:9
12
Mak 13:22
Nitori awọn eke Kristi, ati awọn eke woli yio dide, nwọn o si fi àmi ati ohun iyanu hàn, tobẹ̃ bi o ṣe iṣe, nwọn iba tàn awọn ayanfẹ pãpã.
Ṣàwárí Mak 13:22
13
Mak 13:24-25
Ṣugbọn li ọjọ wọnni, lẹhin ipọnju na, õrùn yio ṣõkun, oṣupá kì yio si fi imọle rẹ̀ hàn; Awọn irawọ oju ọrun yio já silẹ̀, ati agbara ti mbẹ li ọrun li a o si mì titi.
Ṣàwárí Mak 13:24-25
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò