1
Num 13:30
Bibeli Mimọ
Kalebu si pa awọn enia lẹnu mọ́ niwaju Mose, o si wipe, Ẹ jẹ ki a gòke lọ lẹ̃kan, ki a si gbà a; nitoripe awa le ṣẹ́ ẹ.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Num 13:30
2
Num 13:33
Ati nibẹ̀ li awa gbé ri awọn omirán, awọn ọmọ Anaki ti o ti inu awọn omirán wá: awa si dabi ẹlẹnga li oju ara wa, bẹ̃li awa si ri li oju wọn.
Ṣàwárí Num 13:33
3
Num 13:31
Ṣugbọn awọn ọkunrin ti o bá a gòke lọ wipe, Awa kò le gòke tọ̀ awọn enia na lọ; nitoriti nwọn lagbara jù wa lọ.
Ṣàwárí Num 13:31
4
Num 13:32
Nwọn si mú ìhin buburu ti ilẹ na, ti nwọn ti ṣe amí wá fun awọn ọmọ Israeli, wipe, Ilẹ na ti awa là já lati ṣe amí rẹ̀, ilẹ ti imu awọn enia rẹ̀ jẹ ni; ati gbogbo enia ti awa ri ninu rẹ̀ jẹ́ enia ti o ṣigbọnlẹ.
Ṣàwárí Num 13:32
5
Num 13:27
Nwọn si rò fun u, nwọn si wipe, Awa dé ilẹ na nibiti iwọ gbé rán wa lọ, nitõtọ li o nṣàn fun warà ati fun oyin; eyi si li eso rẹ̀.
Ṣàwárí Num 13:27
6
Num 13:28
Ṣugbọn alagbara ni awọn enia ti ngbé inu ilẹ na, ilu olodi si ni ilu wọn, nwọn tobi gidigidi: ati pẹlupẹlu awa ri awọn ọmọ Anaki nibẹ̀.
Ṣàwárí Num 13:28
7
Num 13:29
Awọn ara Amaleki si ngbé ilẹ ìha gusù: ati awọn Hitti, ati awọn Jebusi, ati awọn Amori, ngbé ori-òke: awọn ara Kenaani si ngbé ẹba okun, ati ni àgbegbe Jordani.
Ṣàwárí Num 13:29
8
Num 13:26
Nwọn si lọ nwọn tọ̀ Mose wá, ati Aaroni, ati gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ni ijù Parani, ni Kadeṣi; nwọn si mú ọ̀rọ pada tọ̀ wọn wá, ati gbogbo ijọ, nwọn si fi eso ilẹ na hàn wọn.
Ṣàwárí Num 13:26
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò