1
Owe 1:7-8
Bibeli Mimọ
Ibẹ̀ru Oluwa ni ipilẹṣẹ ìmọ; ṣugbọn awọn aṣiwere gàn ọgbọ́n ati ẹkọ́. Ọmọ mi, gbọ́ ẹkọ́ baba rẹ, ki iwọ ki o má si kọ̀ ofin iya rẹ silẹ
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Owe 1:7-8
2
Owe 1:32-33
Nitoripe irọra awọn alaimọ̀kan ni yio pa wọn, ati alafia awọn aṣiwere ni yio pa wọn run. Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fetisi mi yio ma gbe lailewu, yio si farabalẹ kuro ninu ibẹ̀ru ibi.
Ṣàwárí Owe 1:32-33
3
Owe 1:5
Ọlọgbọ́n yio gbọ́, yio si ma pọ̀ si i li ẹkọ́; ati ẹni oye yio gba igbimọ̀ ọgbọ́n
Ṣàwárí Owe 1:5
4
Owe 1:10
Ọmọ mi, bi awọn ẹlẹṣẹ̀ ba tàn ọ, iwọ má ṣe gbà.
Ṣàwárí Owe 1:10
5
Owe 1:1-4
OWE Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israeli; Lati mọ̀ ọgbọ́n ati ẹkọ́; lati mọ̀ ọ̀rọ oye; Lati gbà ẹkọ́ ọgbọ́n, ododo, ati idajọ, ati aiṣègbe; Lati fi oye fun alaimọ̀kan, lati fun ọdọmọkunrin ni ìmọ ati ironu.
Ṣàwárí Owe 1:1-4
6
Owe 1:28-29
Nigbana ni ẹnyin o kepè mi, ṣugbọn emi kì yio dahùn; nwọn o ṣafẹri mi ni kùtukùtu, ṣugbọn nwọn kì yio ri mi: Nitori ti nwọn korira ìmọ, nwọn kò si yàn ibẹ̀ru Oluwa.
Ṣàwárí Owe 1:28-29
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò