1
O. Daf 143:10
Bibeli Mimọ
Kọ́ mi lati ṣe ohun ti o wù ọ: nitori iwọ li Ọlọrun mi: jẹ ki ẹmi rẹ didara fà mi lọ ni ilẹ ti o tẹju.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí O. Daf 143:10
2
O. Daf 143:8
Mu mi gbọ́ iṣeun-ifẹ rẹ li owurọ; nitori iwọ ni mo gbẹkẹle: mu mi mọ̀ ọ̀na ti emi iba ma tọ̀; nitori mo gbé ọkàn mi soke si ọ.
Ṣàwárí O. Daf 143:8
3
O. Daf 143:9
Oluwa, gbà mi lọwọ awọn ọta mi: ọdọ rẹ ni mo sa pamọ́ si.
Ṣàwárí O. Daf 143:9
4
O. Daf 143:11
Oluwa, sọ mi di ãye nitori orukọ rẹ: ninu ododo rẹ mu ọkàn mi jade ninu iṣẹ́.
Ṣàwárí O. Daf 143:11
5
O. Daf 143:1
OLUWA, gbọ́ adura mi, fi eti si ẹ̀bẹ mi; ninu otitọ rẹ dá mi lohùn ati ninu ododo rẹ.
Ṣàwárí O. Daf 143:1
6
O. Daf 143:7
Oluwa, gbọ́ temi nisisiyi; o rẹ̀ ọkàn mi tan; máṣe pa oju rẹ mọ́ kuro lara mi, ki emi ki o má bà dabi awọn ti o lọ sinu ihò.
Ṣàwárí O. Daf 143:7
7
O. Daf 143:5
Emi ranti ọjọ atijọ; emi ṣe àṣaro iṣẹ rẹ gbogbo, emi nronu iṣẹ ọwọ rẹ.
Ṣàwárí O. Daf 143:5
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò