1
O. Daf 40:1-2
Bibeli Mimọ
NI diduro emi duro de Oluwa; o si dẹti si mi, o si gbohun ẹkún mi. O si mu mi gòke pẹlu lati inu iho iparun jade wá, lati inu erupẹ ẹrẹ̀, o si fi ẹsẹ mi ka ori apata, o si fi iṣisẹ mi lelẹ.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí O. Daf 40:1-2
2
O. Daf 40:3
O si fi orin titun si mi li ẹnu, ani orin iyìn si Ọlọrun wa: ọ̀pọ enia ni yio ri i, ti yio si bẹ̀ru, ti yio si gbẹkẹle Oluwa.
Ṣàwárí O. Daf 40:3
3
O. Daf 40:4
Ibukún ni fun ọkunrin na ti o fi Oluwa ṣe igbẹkẹle rẹ̀, ti kò si ka onirera si, tabi iru awọn ti nyà si iha eke.
Ṣàwárí O. Daf 40:4
4
O. Daf 40:8
Inu mi dùn lati ṣe ifẹ rẹ, Ọlọrun mi, nitõtọ, ofin rẹ mbẹ li aiya mi.
Ṣàwárí O. Daf 40:8
5
O. Daf 40:11
Iwọ máṣe fa ãnu rẹ ti o rọnu sẹhin kuro lọdọ mi, Oluwa: ki iṣeun-ifẹ rẹ ati otitọ rẹ ki o ma pa mi mọ́ nigbagbogbo.
Ṣàwárí O. Daf 40:11
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò