1
Ifi 2:4
Bibeli Mimọ
Ṣugbọn eyi ni mo ri wi si ọ, pe, iwọ ti fi ifẹ rẹ iṣaju silẹ.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Ifi 2:4
2
Ifi 2:5
Nitorina ranti ibiti iwọ gbé ti ṣubu, ki o si ronupiwada, ki o si ṣe iṣẹ iṣaju; bi kò si ṣe bẹ̃, emi ó si tọ̀ ọ wá, emi o si ṣí ọpá fitila rẹ kuro ni ipò rẹ̀, bikoṣe bi iwọ ba ronupiwada.
Ṣàwárí Ifi 2:5
3
Ifi 2:10
Máṣe bẹ̀ru ohunkohun tì iwọ mbọ̀ wá jiya rẹ̀: kiyesi i, Èṣu yio gbé ninu nyin jù sinu tubu, ki a le dán nyin wò; ẹnyin o si ni ipọnju ni ijọ mẹwa: iwọ sa ṣe olõtọ de oju ikú, emi ó si fi ade ìye fun ọ.
Ṣàwárí Ifi 2:10
4
Ifi 2:7
Ẹniti o ba li etí ki o gbọ́ ohun ti Ẹmí nsọ fun awọn ijọ. Ẹniti o ba ṣẹgun ni emi o fi eso igi ìye nì fun jẹ, ti mbẹ larin Paradise Ọlọrun.
Ṣàwárí Ifi 2:7
5
Ifi 2:2
Emi mọ̀ iṣẹ rẹ, ati lãlã rẹ, ati ìfarada rẹ, ati bi ara rẹ kò ti gba awọn ẹni buburu: ati bi iwọ si ti dan awọn ti npè ara wọn ni aposteli, ti nwọn kì sì iṣe bẹ̃ wo, ti iwọ si ri pe eleke ni wọn
Ṣàwárí Ifi 2:2
6
Ifi 2:3
Ti iwọ si farada ìya, ati nitori orukọ mi ti o si fi aiya rán, ti ãrẹ̀ kò si mu ọ.
Ṣàwárí Ifi 2:3
7
Ifi 2:17
Ẹniti o ba li etí, ki o gbọ́ ohun ti Ẹmí nsọ fun awọn ijọ. Ẹniti o ba ṣẹgun li emi o fi manna ti o pamọ́ fun jẹ, emi o si fun u li okuta funfun kan, ati sara okuta na orukọ titun ti a o kọ si i, ti ẹnikẹni kò mọ̀ bikoṣe ẹniti o gbà a.
Ṣàwárí Ifi 2:17
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò