1
Ifi 20:15
Bibeli Mimọ
Bi a ba si ri ẹnikẹni ti a kò kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe ìye, a sọ ọ sinu adagun iná.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Ifi 20:15
2
Ifi 20:12
Mo si ri awọn okú, ati ewe ati àgba, nwọn duro niwaju itẹ; a si ṣi awọn iwe silẹ; a si ṣí awọn iwe miran kan silẹ ti iṣe iwe ìye: a si ṣe idajọ fun awọn okú lati inu ohun ti a ti kọ sinu awọn iwe na, gẹgẹ bi iṣẹ wọn.
Ṣàwárí Ifi 20:12
3
Ifi 20:13-14
Okun si jọ awọn okú ti mbẹ ninu rẹ̀ lọwọ; ati ikú ati ipo-okú si jọ okú ti o wà ninu wọn lọwọ: a si ṣe idajọ wọn olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ wọn. Ati ikú ati ipo-okú li a si sọ sinu adagun iná. Eyi ni ikú keji.
Ṣàwárí Ifi 20:13-14
4
Ifi 20:11
Mo si ri itẹ́ funfun nla kan, ati ẹni ti o joko lori rẹ̀, niwaju ẹniti aiye ati ọrun fò lọ; a kò si ri ãye fun wọn mọ́.
Ṣàwárí Ifi 20:11
5
Ifi 20:7-8
Nigbati ẹgbẹrun ọdún na ba si pé, a o tú Satani silẹ kuro ninu tubu rẹ̀. Yio si jade lọ lati mã tàn awọn orilẹ-ède ti mbẹ ni igun mẹrẹrin aiye jẹ, Gogu ati Magogu, lati gbá wọn jọ si ogun: awọn ti iye wọn dabi iyanrìn okun.
Ṣàwárí Ifi 20:7-8
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò