1
Rom 14:17-18
Bibeli Mimọ
Nitori ijọba Ọlọrun kì iṣe jijẹ ati mimu; bikoṣe ododo, ati alafia, ati ayọ̀ ninu Ẹmí Mimọ́. Nitori ẹniti o ba nsìn Kristi ninu nkan wọnyi, li o ṣe itẹwọgbà lọdọ Ọlọrun, ti o si ni iyin lọdọ enia.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Rom 14:17-18
2
Rom 14:8
Nitori bi a ba wà lãye, awa wà lãye fun Oluwa; bi a ba si kú, awa kú fun Oluwa: nitorina bi a wà lãye, tabi bi a kú ni, ti Oluwa li awa iṣe.
Ṣàwárí Rom 14:8
3
Rom 14:19
Njẹ nitorina, ki awa ki o mã lepa ohun ti iṣe ti alafia, ati ohun ti awa o fi gbe ara wa ró.
Ṣàwárí Rom 14:19
4
Rom 14:13
Nitorina ẹ máṣe jẹ ki a tun mã da ara wa lẹjọ mọ́: ṣugbọn ẹ kuku mã ṣe idajọ eyi, ki ẹnikẹni máṣe fi ohun ikọsẹ tabi ohun idugbolu si ọ̀na arakunrin rẹ̀.
Ṣàwárí Rom 14:13
5
Rom 14:11-12
Nitori a ti kọ ọ pe, Oluwa wipe, Bi emi ti wà, gbogbo ẽkún ni yio kunlẹ fun mi, ati gbogbo ahọn ni yio si jẹwọ fun Ọlọrun. Njẹ nitorina, olukuluku wa ni yio jihin ara rẹ̀ fun Ọlọrun.
Ṣàwárí Rom 14:11-12
6
Rom 14:1
ṢUGBỌN ẹniti o ba ṣe ailera ni igbagbọ́ ẹ gbà a, li aitọpinpin iṣiyemeji rẹ̀.
Ṣàwárí Rom 14:1
7
Rom 14:4
Tani iwọ ti ndá ọmọ-ọdọ ẹlomĩ lẹjọ? loju oluwa rẹ̀ li o duro, tabi ti o ṣubu. Nitotọ a o si mu u duro: nitori Oluwa ni agbara lati mu u duro.
Ṣàwárí Rom 14:4
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò