1
1 Kọrinti 3:16
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ṣé ẹ̀yin kò tilẹ̀ mọ̀ pé tẹmpili Ọlọ́run ni ẹ̀yin jẹ́? Àti pẹ̀lú pe Ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú yín?
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí 1 Kọrinti 3:16
2
1 Kọrinti 3:11
Nítorí kò sí ẹlòmíràn tó le fi ìpìlẹ̀ tòótọ́ mìíràn lélẹ̀ ju èyí tí a fi lélẹ̀ àní Jesu Kristi ni ìpìlẹ̀ náà.
Ṣàwárí 1 Kọrinti 3:11
3
1 Kọrinti 3:7
Ǹjẹ́ kì í ṣe ẹni tí ó ń gbìn nǹkan kan, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ẹni tí ń bomirin; bí kò ṣe Ọlọ́run tí ó ń mú ìbísí wá.
Ṣàwárí 1 Kọrinti 3:7
4
1 Kọrinti 3:9
A ń bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ pọ̀ ni, ẹ̀yin pàápàá sì jẹ́ ọgbà ohun ọ̀gbìn fún Ọlọ́run, kì í ṣe fún wa, ilé Ọlọ́run ni yín, kì í ṣe ilé tiwa.
Ṣàwárí 1 Kọrinti 3:9
5
1 Kọrinti 3:13
Iṣẹ́ olúkúlùkù ènìyàn yóò hàn, nítorí ọjọ́ náà yóò fi í hàn, nítorí pé nínú iná ni a ó ti fihàn, iná náà yóò sì dán irú iṣẹ́ èyí tí olúkúlùkù ṣe wò.
Ṣàwárí 1 Kọrinti 3:13
6
1 Kọrinti 3:8
Ẹni tí ó ń gbìn àti ẹni tí ó ń bu omi rín ní ìrònú kan àti èrèdí kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yóò gba èrè tirẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe é kárakára tó.
Ṣàwárí 1 Kọrinti 3:8
7
1 Kọrinti 3:18
Kí ẹnikẹ́ni, má ṣe tan ara rẹ̀ jẹ mọ́. Bí ẹnikẹ́ni yín nínú ayé yìí ba rò pé òun gbọ́n, ẹ jẹ́ kí ó di òmùgọ̀ kí ó bá a le è gbọ́n.
Ṣàwárí 1 Kọrinti 3:18
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò