1
1 Samuẹli 17:45
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Dafidi sì wí fún Filistini pé, “Ìwọ dojú ìjà kọ mí pẹ̀lú idà, ọ̀kọ̀ àti ọfà, ṣùgbọ́n èmi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ pẹ̀lú orúkọ OLúWA àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Israẹli tí ìwọ tí gàn.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí 1 Samuẹli 17:45
2
1 Samuẹli 17:47
Gbogbo àwọn tí ó péjọ níbí ni yóò mọ̀ pé kì í ṣe nípa ọ̀kọ̀ tàbí idà ni OLúWA fi ń gbàlà; ogun náà ti OLúWA ni, yóò sì fi gbogbo yín lé ọwọ́ wa.”
Ṣàwárí 1 Samuẹli 17:47
3
1 Samuẹli 17:37
OLúWA tí ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìhàlẹ̀ kìnnìún àti ti ìhàlẹ̀ àmọ̀tẹ́kùn yóò gbà mí kúrò lọ́wọ́ Filistini yìí.” Saulu wí fún Dafidi pé, “Lọ kí OLúWA wà pẹ̀lú rẹ.”
Ṣàwárí 1 Samuẹli 17:37
4
1 Samuẹli 17:46
Lónìí yìí ni OLúWA yóò fi ọ́ lé mi lọ́wọ́, èmi yóò sì pa ọ́, èmi yóò sì gé orí rẹ. Lónìí èmi yóò fi òkú ogun Filistini fún ẹyẹ ojú ọ̀run àti fún ẹranko igbó, gbogbo ayé yóò sì mọ̀ pé Ọlọ́run wà ní Israẹli.
Ṣàwárí 1 Samuẹli 17:46
5
1 Samuẹli 17:40
Nígbà náà, ó sì mú ọ̀pá rẹ̀ lọ́wọ́, ó ṣá òkúta dídán márùn-ún létí odò, ó kó wọn sí àpò olùṣọ́-àgùntàn tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀ pẹ̀lú kànnàkànnà, ó sì súnmọ́ Filistini náà.
Ṣàwárí 1 Samuẹli 17:40
6
1 Samuẹli 17:32
Dafidi sọ fún Saulu pé, “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítorí Filistini yìí, ìránṣẹ́ rẹ yóò lọ láti bá a jà.”
Ṣàwárí 1 Samuẹli 17:32
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò