1
Daniẹli 7:14
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
A sì fi ìjọba, ògo àti agbára ilẹ̀ ọba fún un; gbogbo ènìyàn, orílẹ̀-èdè àti èdè gbogbo wọn wólẹ̀ fún un. Ìjọba rẹ̀, ìjọba ayérayé ni, èyí tí kò le è kọjá, ìjọba rẹ̀ kò sì le è díbàjẹ́ láéláé.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Daniẹli 7:14
2
Daniẹli 7:13
“Nínú ìran mi ní òru mo wò, mo rí ẹnìkan tí ó dúró sí iwájú u mi, ó rí bí Ọmọ ènìyàn, ó ń bọ̀ wá nínú àwọsánmọ̀ ọ̀run, ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ ẹni ìgbàanì, a sì mú u wá sí iwájú rẹ̀.
Ṣàwárí Daniẹli 7:13
3
Daniẹli 7:27
Nígbà náà, ni a ó gba ìjọba, agbára àti títóbi ìjọba rẹ̀ ní abẹ́ gbogbo ọ̀run, a ó sì fi fún àwọn ẹni mímọ́, àwọn ènìyàn Ọ̀gá-ògo. Ìjọba rẹ̀ yóò jẹ́ ìjọba títí ayé, gbogbo aláṣẹ ni yóò máa ṣe ìgbọ́ràn sí i, wọn yóò sì máa sìn ín.’
Ṣàwárí Daniẹli 7:27
4
Daniẹli 7:18
Ṣùgbọ́n, ẹni mímọ́ ti Ọ̀gá-ògo ni yóò gba ìjọba náà, yóò sì jogún un rẹ títí láé àti títí láéláé.’
Ṣàwárí Daniẹli 7:18
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò