1
Deuteronomi 28:1
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Bí ìwọ bá gbọ́rọ̀ sí OLúWA Ọlọ́run rẹ ní kíkún kí o sì kíyèsára láti tẹ̀lé gbogbo ohun tí ó pàṣẹ tí mo fi fún ọ lónìí, OLúWA Ọlọ́run rẹ yóò gbé ọ lékè ju gbogbo orílẹ̀-èdè ayé lọ.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Deuteronomi 28:1
2
Deuteronomi 28:2
Gbogbo ìbùkún yìí yóò wá sórí rẹ yóò sì máa bá ọ lọ bí o bá gbọ́rọ̀ sí OLúWA Ọlọ́run rẹ
Ṣàwárí Deuteronomi 28:2
3
Deuteronomi 28:13
OLúWA yóò fi ọ́ ṣe orí, ìwọ kì yóò sì jẹ́ ìrù. Bí o bá fi etí sílẹ̀ sí àṣẹ OLúWA Ọlọ́run rẹ tí mo fi fún ọ kí o sì máa rọra tẹ̀lé wọn, ìwọ yóò máa wà lókè, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò wà ní ìsàlẹ̀ láé.
Ṣàwárí Deuteronomi 28:13
4
Deuteronomi 28:12
OLúWA yóò ṣí ọ̀run sílẹ̀, ìṣúra rere rẹ̀ fún ọ, láti rọ òjò sórí ilẹ̀ rẹ ní àsìkò rẹ àti láti bùkún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ. Ìwọ yóò yá ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ṣùgbọ́n ìwọ kò ní í yá lọ́wọ́ ẹnìkankan.
Ṣàwárí Deuteronomi 28:12
5
Deuteronomi 28:7
OLúWA yóò gbà fún ọ pé gbogbo ọ̀tá tí ó dìde sí ọ yóò bì ṣubú níwájú rẹ. Wọn yóò tọ̀ ọ́ wá ní ọ̀nà kan ṣùgbọ́n wọn yóò sá fún ọ ní ọ̀nà méje.
Ṣàwárí Deuteronomi 28:7
6
Deuteronomi 28:8
OLúWA yóò rán ìbùkún sí ọ àti sí ohun gbogbo tí o bá dáwọ́ rẹ lé. OLúWA Ọlọ́run rẹ yóò bùkún un fún ọ nínú ilẹ̀ tí ó ń fi fún ọ.
Ṣàwárí Deuteronomi 28:8
7
Deuteronomi 28:6
Ìbùkún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá wọlé, ìbùkún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá jáde.
Ṣàwárí Deuteronomi 28:6
8
Deuteronomi 28:3
Ìbùkún ni fún ọ ni ìlú, ìbùkún ni fún ọ ní oko.
Ṣàwárí Deuteronomi 28:3
9
Deuteronomi 28:4
Ìbùkún ni fún ọmọ inú rẹ, àti èso ilẹ̀ rẹ, àti irú ohun ọ̀sìn rẹ àti ìbísí i màlúù rẹ àti ọmọ àgùntàn rẹ.
Ṣàwárí Deuteronomi 28:4
10
Deuteronomi 28:9
OLúWA yóò fi ọ́ múlẹ̀ bí ènìyàn mímọ́, bí ó ti ṣe ìlérí fún ọ lórí ìbúra, bí o bá pa àṣẹ OLúWA Ọlọ́run rẹ mọ́ tí o sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
Ṣàwárí Deuteronomi 28:9
11
Deuteronomi 28:5
Ìbùkún ni fún agbọ̀n rẹ àti fún ọpọ́n ipò ìyẹ̀fun rẹ.
Ṣàwárí Deuteronomi 28:5
12
Deuteronomi 28:11
OLúWA yóò fi àlàáfíà fún ọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, fún ọmọ inú rẹ, irú ohun ọ̀sìn rẹ àti àwọn èso ilẹ̀ rẹ ní ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá rẹ láti fún ọ.
Ṣàwárí Deuteronomi 28:11
13
Deuteronomi 28:10
Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ayé yóò rí i pé a pè ọ́ ní orúkọ OLúWA, wọn yóò sì bẹ̀rù rẹ.
Ṣàwárí Deuteronomi 28:10
14
Deuteronomi 28:14
Má ṣe yà sọ́tùn tàbí sósì kúrò, nínú èyíkéyìí àwọn àṣẹ tí mo fi fún ọ ní òní yìí, kí o má ṣe tẹ̀lé àwọn ọlọ́run mìíràn láti máa sìn wọ́n.
Ṣàwárí Deuteronomi 28:14
15
Deuteronomi 28:15
Ṣùgbọ́n bí o kò bá gbọ́ ti OLúWA Ọlọ́run rẹ kí o sì rọra máa tẹ̀lé gbogbo àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mò ń fún ọ lónìí, gbogbo ègún yìí yóò wá sórí rẹ yóò sì máa bá ọ lọ
Ṣàwárí Deuteronomi 28:15
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò