1
Gẹnẹsisi 37:5
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Josẹfu lá àlá kan, nígbà tí ó sì sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 37:5
2
Gẹnẹsisi 37:3
Israẹli sì fẹ́ràn Josẹfu ju gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ tókù lọ, nítorí ní ọjọ́ ogbó rẹ̀ ni ó bí i. O sì dá aṣọ aláràbarà tí ó kún fún onírúurú ọnà lára fún un.
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 37:3
3
Gẹnẹsisi 37:4
Nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ rí i pé baba àwọn fẹ́ràn rẹ̀ ju gbogbo wọn lọ, wọ́n kórìíra rẹ̀, wọ́n sì ń fi ẹ̀tanú bá a gbé, kò sì sí àlàáfíà láàrín wọn.
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 37:4
4
Gẹnẹsisi 37:9
O sì tún lá àlá mìíràn, ó sì tún sọ ọ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀. Ó wí pé, ẹ tẹ́tí sí mi, “Mo tún lá àlá mìíràn, wò ó, oòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀ mọ́kànlá ń foríbalẹ̀ fún mi.”
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 37:9
5
Gẹnẹsisi 37:11
Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì ń ṣe ìlara rẹ̀ ṣùgbọ́n baba rẹ̀ pa ọ̀rọ̀ náà mọ́ lọ́kàn rẹ̀.
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 37:11
6
Gẹnẹsisi 37:6-7
O wí fún wọn pé, “Ẹ fetí sí àlá tí mo lá: Sá à wò ó, àwa ń yí ìtí ọkà nínú oko, ó sì ṣe ìtí ọkà tèmi sì dìde dúró ṣánṣán, àwọn ìtí ọkà tiyín sì dúró yí ìtí tèmi ká, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún un.”
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 37:6-7
7
Gẹnẹsisi 37:20
“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á. Kí a sì ju òkú rẹ̀ sínú kòtò, a ó sì wí pé, ẹranko búburú ni ó pa á, kí a máa wo ọ̀nà tí àlá rẹ̀ yóò gbà ṣẹ.”
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 37:20
8
Gẹnẹsisi 37:28
Nítorí náà, nígbà tí àwọn oníṣòwò ara Midiani ń kọjá, àwọn arákùnrin Josẹfu fà á jáde láti inú kòtò, wọ́n sì tà á fún àwọn ará Iṣmaeli ní ogún owó wúrà, wọ́n sì mú Josẹfu lọ sí ilẹ̀ Ejibiti.
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 37:28
9
Gẹnẹsisi 37:19
“Alálàá ni ń bọ̀ yìí,” ni wọ́n ń wí fún ara wọn.
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 37:19
10
Gẹnẹsisi 37:18
Ṣùgbọ́n bí wọ́n sì ti rí i tí ń bọ̀ lókèèrè, kí ó sì tó dé ọ̀dọ̀ wọn, wọn gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á.
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 37:18
11
Gẹnẹsisi 37:22
Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ẹ má ṣe fọwọ́ kàn án, ẹ kúkú jù ú sínú kòtò láààyè nínú aginjù níbí.” Reubeni sọ èyí, kí ó ba à le gbà á kúrò lọ́wọ́ wọn, kí ó sì dá a padà lọ fún baba rẹ̀.
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 37:22
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò