“Juda, àwọn arákùnrin rẹ yóò yìn ọ,
ọwọ́ rẹ yóò wà ní ọrùn àwọn ọ̀tá rẹ,
àwọn ọmọkùnrin baba rẹ yóò foríbalẹ̀ fún ọ.
Ọmọ kìnnìún ni ọ́, ìwọ Juda,
o darí láti igbó ọdẹ, ọmọ mi.
Bí i kìnnìún, o ba mọ́lẹ̀, o sì sùn sílẹ̀ bí i abo kìnnìún,
Ta ni ó tó bẹ́ẹ̀, kí o lé e dìde?