1
Isaiah 51:12
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
“Èmi, àní Èmi, èmi ni ẹni tí ó tù ọ́ nínú. Ta ni ọ́ tí o fi ń bẹ̀rù ènìyàn ẹlẹ́ran ara, àti ọmọ ènìyàn, tí ó jẹ́ koríko lásán
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Isaiah 51:12
2
Isaiah 51:16
Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ mo sì ti fi òjìji ọwọ́ mi bò ọ́ Èmi tí mo tẹ́ àwọn ọ̀run sí ààyè rẹ̀, ẹni tí ó fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀, àti ẹni tí ó sọ fún Sioni pé, ‘Ẹ̀yin ni ènìyàn mi.’ ”
Ṣàwárí Isaiah 51:16
3
Isaiah 51:7
“Ẹ gbọ́ mi, ẹ̀yin tí ó mọ ohun òtítọ́, ẹ̀yin ènìyàn tí ó ní òfin mi ní àyà yín: Ẹ má ṣe bẹ̀rù ẹ̀gàn àwọn ènìyàn tàbí kí ẹ̀rù èébú wọn já a yín láyà.
Ṣàwárí Isaiah 51:7
4
Isaiah 51:3
Dájúdájú, OLúWA yóò tu Sioni nínú yóò sì bojú àánú wo gbogbo ahoro rẹ̀; Òun yóò sọ gbogbo aṣálẹ̀ rẹ̀ di Edeni, àti aṣálẹ̀ rẹ̀ yóò rí bí ọgbà OLúWA. Ayọ̀ àti inú dídùn ni a ó rí nínú rẹ̀, ọpẹ́ àti ariwo orín kíkọ.
Ṣàwárí Isaiah 51:3
5
Isaiah 51:11
Àwọn ẹni ìràpadà OLúWA yóò padà wá. Wọn yóò wọ Sioni wá pẹ̀lú orin kíkọ; ayọ̀ ayérayé ni yóò sì bo orí wọn. Ayọ̀ àti inú dídùn yóò sì bà lé wọn ìbànújẹ́ àti ìtìjú yóò sì sá kúrò.
Ṣàwárí Isaiah 51:11
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò