Èyí ni ọ̀rọ̀ OLúWA tó tọ wòlíì Jeremiah wá nípa àwọn Filistini, kí ó tó di pé Farao dojúkọ Gasa.
Báyìí ni OLúWA wí:
“Wo bí omi ti ń ru sókè ní àríwá,
wọn ó di odò tí ń bo bèbè mọ́lẹ̀.
Wọn kò ní borí ilẹ̀ àti ohun gbogbo tó wà lórí rẹ̀,
ìlú àti àwọn tó ń gbé nínú wọn.
Àwọn ènìyàn yóò kígbe,
gbogbo olùgbé ilẹ̀ náà yóò hu