1
Nehemiah 8:10
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Nehemiah wí pé, “Ẹ lọ kí ẹ gbádùn oúnjẹ tí ẹ yàn láàyò kí ẹ sì mú ohun dídùn, kí ẹ sì mú díẹ̀ ránṣẹ́ sí àwọn tí kò ní. Ọjọ́ yìí, mímọ́ ni fún Olúwa wa. Ẹ má ṣe banújẹ́, nítorí ayọ̀ OLúWA ni agbára yín.”
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Nehemiah 8:10
2
Nehemiah 8:9
Nígbà náà ni Nehemiah tí ó jẹ́ baálẹ̀, Esra àlùfáà àti akọ̀wé, àti àwọn Lefi tí wọ́n ń kọ́ àwọn ènìyàn wí fún gbogbo wọn pé, “Ọjọ́ yìí jẹ́ ọjọ́ mímọ́ fún OLúWA Ọlọ́run yín. Ẹ má ṣe ṣọ̀fọ̀ tàbí sọkún” Nítorí gbogbo àwọn ènìyàn ti ń sọkún bí wọ́n ti ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ inú òfin náà.
Ṣàwárí Nehemiah 8:9
3
Nehemiah 8:6
Esra yin OLúWA, Ọlọ́run alágbára; gbogbo ènìyàn gbé ọwọ́ wọn sókè, wọ́n sì wí pé “Àmín! Àmín!” Nígbà náà ni wọ́n wólẹ̀ wọ́n sì sin OLúWA ní ìdojúbolẹ̀.
Ṣàwárí Nehemiah 8:6
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò