1
Òwe 3:5-6
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Gbẹ́kẹ̀lé OLúWA pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ má ṣe sinmi lé òye ara à rẹ; Mọ̀ ọ́n ní gbogbo ọ̀nà rẹ òun yóò sì máa tọ́ ipa ọ̀nà rẹ.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Òwe 3:5-6
2
Òwe 3:7
Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara à rẹ bẹ̀rù OLúWA kí o sì kórìíra ibi.
Ṣàwárí Òwe 3:7
3
Òwe 3:9-10
Fi ọrọ̀ rẹ bọ̀wọ̀ fún OLúWA, pẹ̀lú àkọ́so oko rẹ Nígbà náà ni àká rẹ yóò kún àkúnya àgbá rẹ yóò kún àkúnwọ́sílẹ̀ fún wáìnì tuntun.
Ṣàwárí Òwe 3:9-10
4
Òwe 3:3
Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ àti òtítọ́ ṣíṣe fi ọ́ sílẹ̀ láéláé so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ, kọ wọ́n sí wàláà àyà rẹ.
Ṣàwárí Òwe 3:3
5
Òwe 3:11-12
Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí OLúWA má sì ṣe bínú nígbà tí ó bá ń bá ọ wí, Nítorí OLúWA a máa bá àwọn tí ó fẹ́ràn wí bí baba ti í bá ọmọ tí ó bá nínú dídùn sí wí.
Ṣàwárí Òwe 3:11-12
6
Òwe 3:1-2
Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ mi. Ṣùgbọ́n pa òfin mi mọ́ sí ọkàn rẹ. Nítorí ọjọ́ gígùn, ẹ̀mí gígùn, àti àlàáfíà, ni wọn yóò fi kùn un fún ọ.
Ṣàwárí Òwe 3:1-2
7
Òwe 3:13-15
Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní ìmọ̀, ẹni tí ó tún ní òye sí i Nítorí ó ṣe èrè ju fàdákà lọ ó sì ní èrè lórí ju wúrà lọ. Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ; kò sí ohunkóhun tí a lè fiwé e nínú ohun gbogbo tí ìwọ fẹ́.
Ṣàwárí Òwe 3:13-15
8
Òwe 3:27
Má ṣe fa ọwọ́ ìre sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ṣe tìrẹ, nígbà tí ó bá wà ní ìkápá rẹ láti ṣe ohun kan.
Ṣàwárí Òwe 3:27
9
Òwe 3:19
Nípa ọgbọ́n, OLúWA fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀; nípa òye, ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn
Ṣàwárí Òwe 3:19
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò